Akọ̀ròyìn ní Ghana yóò gba $18m owó ìtanràn bó ṣe jàre ẹjọ́ ìbanilórúkọjẹ́ tó pé aṣòfin kan

Anas ree, akọroyin abẹnu to maa n fi irun boju rẹ ki wọn ma baa da a mọ

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Anas ree, akọroyin abẹnu to maa n fi irun boju rẹ ki wọn ma baa da a mọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Anas Aremeyaw Anas, akọroyin ọmọ orilẹede Ghana kan ni ile-ẹjọ ti da lare lori iṣẹ iwadii to ṣe fun BBC, ti ọkan ninu awọn aṣofin tẹlẹ niluu naa, Kennedy Agyapong, si tori ẹ pe e ni ọdaran ati apaayan.

Kootu to jokoo lorilẹede America lo paṣẹ, pe ki aṣofin naa san owo tiye rẹ jẹ $18m fun Anas gẹgẹ bii owo itanran ibanilorukọjẹ.

Ọmọ ile igbimọ aṣofin ni Kennedy Agyapong tẹlẹ lorilẹede Ghana.

Ọdun 2018 ni Anas, akọroyin to n tọpinpin labẹnu naa gbe iṣẹ iwadii rẹ jade nipa ikowojẹ.

Anas tu aṣiri ikowojẹ lẹka ere idaraya bọọlu afẹsẹgba ni Ghana ati lawọn ibo mi-in, eyi si ta ba Agyapong.

Kí ni ọmọ ile igbimọ tẹlẹ naa ṣe lẹyin èyí?

Lati fi aidunnu rẹ han si iṣẹ iwadii Anas, Agyapong Farahan lori eto kan, nibẹ lo si ti sọ awọn ọrọ ibanilorukọjẹ nipa akọroyin naa.

Ni 2021, aṣofin tẹlẹ naa pe Anas ni ọdaran lori afẹfẹ, bẹẹ lo si tun ni akọroyin yii lo pa oniroyin ẹgbẹ rẹ torukọ iyẹn n jẹ Ahmed Suale.

Ọrọ yii ko ba Anas lara mu.

O ti koju iru nnkan bayii ri lọdun meje sẹyin to si pe ẹjọ, ṣugbọn wọn ko da a lare.

Nigba ti eyi tun ṣẹlẹ ni 2021, oniroyin naa ko duro lorilẹede rẹ nipa ẹjọ pipe, ilẹ America lo gba lọ.

New Jersey ti Agyapong to fi ẹsun kan ni ile si lo gbe ẹjọ ibanilorukọjẹ naa lọ.

Adajọ mẹjọ lo jokoo lori ẹsun naa, wọn si da Kennedy Agyapong lẹbi.

Kootu paṣẹ pe ki aṣofin tẹlẹ naa san $18m (£14m) bii owo itanran ibanilorukọjẹ fun Anas.

'Bí wọ́n tiẹ̀ fẹ́ẹ́ pa mí, mo máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ '

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n fi idunnu rẹ han ninu idajọ to waye lọjọ Iṣẹgun naa, Anas sọ pe,

" Otitọ ti leke. Iṣẹgun yii ki i ṣe fun emi nikan, bi ko ṣe fun otitọ, ominira akọroyin lati sọrọ ati fun gbogbo ẹni ti ko kọ ohun ti yoo ṣẹlẹ, to jẹ bi wọn yoo ṣe foju iwa ibajẹ han ni wọn gbe dani.

"Ko si bi wọn ṣe le halẹ mọ mi to, ko si iye irọ ti wọn le pa to maa mu mi pada, koda bi wọn ba fẹẹ pa mi, iṣẹ wa n tẹsiwaju lai bẹru, lai ṣojo ni."

Anas lo sọ bẹẹ.

Akọroyin yii to ti gba ọpọ ami ẹyẹ lori iṣẹ iwadii kaakiri agbaye, ṣeleri pe oun yoo maa ba awọn onijẹkujẹ fa a, oun yoo si maa fi oju awọn eeyan keeyan han lode.

Ṣaa, awọn agbẹjọro fun olujẹjọ, sọ pe ko yẹ ki Anas gbe ẹjọ naa lọ si America.

Awọn lọọya naa sọ pe ọrọ ti onibaara awọn sọ lori eto ko ju ohun ti aye mọ si asọdun lọ.

Wọn ni ero ọkan Agyapong lo sọ sita, iyẹn ko yẹ ko di ohun ti wọn yoo maa ka si ibanilorukọjẹ, debi ti wọn yoo maa ni ki kọstọma awọn sanwo gọbọi fun akọroyin to pe e lẹjọ.

Ẹwẹ, awọn ọlọpaa Ghana ti mu afurasi kan lori iku Ahmed Hussein Suale, akọroyin tawọn kan pa ni 2019.

A gbọ pe afurasi naa fi aworan Oloogbe Ahmed toun naa jẹ akọroyin to n ṣe iwadii abẹnu, han pẹlu gbajumọ oloṣelu kan ni Ghana.

Ki Suale too ku ni wọn ni afurasi ti pin fọto naa kiri ori ayelujara.

Bakan naa ni iku Ahmed ni nnkan i ṣe pẹlu iwa ajẹbanu ti wọn fi han pe o n lọ lẹka bọọlu afẹsẹgba ni Ghana.

Gẹgẹ bi BBC Africa Eye ṣe jabọ iwadii rẹ, iṣẹ iwadii naa da lori ituṣu-desalẹ ikoko lati mọ awọn to n ṣe owo ajọ agbabọọlu baṣubaṣu l'Africa.