Irọ́ ni ìjọba Oyo pa lórí oyè Eleruwa, agbára atóbi má ṣeé báwí ni ó lò lé wa lórí - Ìdílé Laribikusi fapá jánú

Ọkan lara awọn idile meji to n jẹ oye Eleruwa ti ilẹ Eruwa ni ijọba ibilẹ Ila-oorun Ibarapa ipinlẹ Ọyọ, idile Laribikusi ti ke gbare wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ko fun awọn ni gbedeke ọjọ mẹrinla lati fa ọmọ oye silẹ, ko to di pe wọn da ọba ti ile ẹjọ rọ loye pada si ori aleefa.
Ninu ọrọ ti wọn sọ ni ibi ipade awọn oniroyin ti idile naa pe l'Ọjọru ninu ọgba awọn akọroyin 'NUJ' to n bẹ ni agbegbe Iyaganku niluu Ibadan, idile Laribikusi sọrọ tako alaye ti Kọmisana fun eto iroyin, Ọmọọba Dọtun Oyelade ṣe saaju asiko yii.
Oyelade ṣaaju sọ pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ati ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, da Ọba Samuel Adebayo Adegbola to wa lati igun Akalako pada si ori itẹ, nitori idile Laribikusi kuna lati fa ọmọ oye silẹ lẹyin gbedeke ọjọ mẹrinla ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fun wọn.

Alaye ti idile naa ṣe ni pe "Aja ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fẹ pa ni wọn sọ ni orukọ buburu".
Wọn ni awọn ti gbaradi lati fa ọmọ oye silẹ lẹyin awuyewuye ọrọ ile ẹjọ to waye lori ipo Eleruwa laarin ọdun 1995 si 2019, gẹgẹ bi awọn ṣe n reti ki ijọba ipinlẹ Ọyọ ke si wọn lati ṣe ohun ti o tọ.
Idile Laribikusi tẹsiwaju wi pe iṣẹ kan ṣoṣo ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ran si awọn ni iwe kan ti wọn fi ranṣe lati ọwọ alaga ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ibarapa, Họnọrebu Kazeem Arogundade lọjọ kẹrin oṣu kọkanla ọdun 2024.
Amọ ọjọ Kiini, oṣu Kọkanla lo wa lori lẹta naa, ṣugbọn wọn ko sọ ohun ti ipade ti awọn fẹ wa ṣe pẹlu alaga ijọba ibilẹ naa da le lori.
Nigba ti awọn aṣoju idile Laribikusi de ibi ipade naa, wọn ṣe alaye wi pe Họnọrebu Kazeem Arogundade beere lọwọ idile naa lati fa ẹni to dagba ju laarin wọn kalẹ ki igbesẹ lati yan Eleruwa tuntun to bẹrẹ.
Sugbọn wọn ni ọrọ naa ko tẹsiwaju tayọ ipade akọkọ ti wọn ṣe nitori alaga ijọba ibilẹ naa bẹ igi dina ohun ti wọn fẹ ṣe.
Lẹyin ọpọlọpọ lilọbibọ, akọwe idile naa, Ọmọọba Abọlade Ijaọla fi orukọ ẹni ti wọn fẹ fa kalẹ, iyẹn Alagba Oladẹjọ Akinlade ranṣẹ si alaga ijọba ibilẹ naa ni Ogunjọ oṣu Kejila ọdun 2024.
Sugbọn esi ti wọn gba lọwọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lọjọ Keje oṣu Kiini ọdun 2025 ni pe ijọba ti yan Eleruwa nitori idile Laribikusi lọra lati gbe awọn igbesẹ ti o tọ.
Wọn ni iwe ẹri ti ọpa ati ijọba ipinlẹ Ọyọ kanju fun ọba ti wọn da pada si ori itẹ lọjọ Kẹfa oṣu Kẹta ọdun 2025 lo fi idi rẹ mulẹ wi pe, ijọba lo agbara atobi ma ṣee bawi lori ọrọ naa.















