AMCON gbẹ́sẹ̀lé gbogbo ǹkan ìní Jimoh Ibrahim tó lé ní N69 bíliọ̀nù

Jimoh Ibrahim

Oríṣun àwòrán, Jimoh Ibrahim

Ajo to n moju to nkan ini ni Naijiria (AMCON) ni oun ti gba awọn nkan ini to se gboogi lọwọ Jimoh Ibrahim to jẹ alakoso ati asagbateru Global Fleet Oil and Gas ati NICON Investment nilu Eko ati Abuja nitori gbese owo biliọnu aadọrin naira.

Ninu atẹjade ti ajọ naa fi sita lo ti ṣalaye pe igbesẹ ti oun gbe wa ni ibamu pẹlu idajọ ile ẹjọ giga ijọba apapọ, ẹka ti ilu Eko lati ẹnu adajọ R. M Aikawa.

AMCON ni "ni ibamu pẹlu idajọ ile ẹjọ ni ọjọru ọjọ kejidinlogun, 2020, lawn fi laṣẹ lati gba nkan ini rẹ to le ni mejila.

Awọn nkan ini naa ni ile ișẹ NICON Investment Limited ti Plot 242, opopona Muhammadu Buhari, Central Business District, Abuja;

NICON Hotels Limited building ti Plot 557, Port-Harcourt Crescent, iyana Gimbiya Street, Abuja ati ile NICON Lekki Limited to wa ni No. 5, Customs Street, nilu Eko.

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?

"Awọn to ku ni ile rẹ ti Abuja International Hotels Limited nlo ni No. 3, Hospital Road, Eko ati Plot 242, Muhammadu Buhari Way, Abuja;

Ile Allied Bank tẹlẹ to wa ni opopona marose Mile 2, Oshodi, Apapa nilu Eko Energy House to wa ni No. 94, opopona Awolowo, Ikoyi, nilu Eko, NICON Building ni No. 40, Madeira, Maitama, Abuja;

Ile igbe kan ni Road 2, House A14, Victoria Garden City, Eko; NICON Hotels Building ni Plot 3, Road 3, Victoria Garden City, Eko ati Ile ti NICON Luxury Hotel's wa ni Garki I, FCT, Abuja.

Àkọlé fídíò, 'Mo ní àṣírí ìyá tó fẹ́ ọmọ rẹ̀ láya fún Boko Haram torí ẹbí rẹ̀'

Ko tan sibẹ̀, yatọ si gbigba gbogbo awọn nkan ini wọnyi, gbogbo apo owo rẹ ni Banki naa kun nkan ti ile ẹjọ ni ki wọn gbẹsẹ le to fi mọ awọn apo owo banki ile iṣẹ gbogbo ti Jimoh Ibrahim ni, lara rẹ ni Global Fleet Oil & Gas Limited ati NICON Investment Limited eyi to wa ninu gbogbo iwe ti wọn fi pẹjọ Suit No. FHL/L/CL/776/2016 ni ijoko ti agbejọro Aikawa ri dajọ lọjọru, ọjọ kẹrin oṣu kọkanla ọdun 2020.

Ile ẹjọ tun ni ki AMCON gba gbogbo ajẹmọnu to le tọ si Jimoh Ibrahim ni awọn ile isẹ rẹ meeeji to wa ni Rẹ-insurance Company Limited PLC ati NICON Insurance company plc, Niferia Stockbrokers Limited ati NICON Trudtees Limited "

Agbẹnusọ AMCON, Jude Nwauzor fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn ile iṣẹ ti ile ejọ fi lede ni AMCON ti gba, o fi ku pe pelu iranwọ ọlọpaa ati ile ẹjọ, ko si wahala kankan to waye lasiko ti AMCON n gba gbogbo nkan wonyi ni ilu Eko ati Abuja

Atunse ofin AMCON ti fun wọn ni agbara lati lati koji ẹnikẹni to ba jẹ owo ti wọn si kọ lati san.