Àláfíà pada sí ìlú Jidari-Polo ní Maiduguri

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ́ ọmọogun kéde pé àlàáfíà ti padà sí ìlú Maiduguri lẹ́yìn ìkọlù àwọn agbébọn Boko Haram lálé ọjọbọ.
Àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà sọ wí pé ikọ ogun wọn ti bẹ́gi dínà ìkọlù ẹgbẹ́ Boko Haram ní agbègbè Jidari-Polo, ìpínlẹ̀ Maiduguri.Àwọn ọmọogun tó ń ṣe aáyan àbò lẹ́kùn ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà ti àdàpè orúkọ wọn ń jẹ́ Operation LAFIYA DOLE ni wọ́n ní wọ́n ti lé àwọn agbébọn náà sígbó.
Ileeṣẹ ológun ní àtìlẹ́yìn àwọn omoogun òfúrufú ni wọ́n fi le wọn pada sígbó.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò BBC Yoruba pẹ̀lú igbákejì supritendentì ní ìlú Maiduguri, ọ̀gágun Edet Okon sọ wípé "lápapọ̀ ènìyàn mẹ́wàá ló bá ìsẹ̀lẹ̀ náà rìn tí márun lára wọ́n jk agbé àdó olóró sùgbọ́n ní báyìí kò síbẹ̀rù ohun gbogbo ti padà bọ̀ sípo".
Ó fi kún un pé ìretí sì wà láti borí ikọ̀ adúnkokò mọọ́ni yìí"
Iléeṣẹ́ ológun ké sí àwọn èèyàn ìlú Maiduguri lati maa ba iṣẹ́ òòjọ́ wọn lọ kí wọ́n sì fi ìròyìn nípa ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá kẹ́ẹ́fín tó àwọn agbófínró lọ́wọ́.
Àwọn afẹ̀míṣòfò Boko Haram, ti ya wọ bárékè Giwa àwọn ológun ní ìlú náà.
Lọ̀rọ̀ di bóòlọ-o-yàá-mi nígbàtí àwọn olùgbé agbègbè bẹ̀rẹ̀ síí sá àsálà fún ẹ̀mí wọn lásìkò tí àwọn Boko Haram dojú ìjà kọ àwọn ọmọ oogun ilẹ̀ Naijiria níbẹ̀ lálẹ́ ọjọọ̀bọ
Pẹ̀lú bí àwọn adarí orílẹ̀èdè Nàìjíríà se ní wọ́n ti boríi ẹgbẹ́ yìí, ẹgbẹ́ ẹsin ò kọkú Boko Haram kò tíì simi ìkọlù ìpànìyàn ní ẹkùn náà.
Ẹ̀wẹ̀, ọ̀gágun Edet Okon ní àwọn òsísẹ́ aláàbo sì wà níbi ìsẹ́lẹ̀ náà láti ríì dájú pé ohun gbogbo ńlọ déédé padà.












