Ekiti Murder: Àwọn agbébọn tún pa Alùfáà Baptist kan ní Ekiti

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oluṣọ aguntan ijọ onitẹbọmi Solution Baptist Church ni ilu Ikẹrẹ Ekiti, Ẹniọwọ Johnson Ọladimeji lawọn agbenipa kan ti pa ni ipinlẹ Ekiti.
Iroyin sọ pe, inu ọkọ rẹ ni wọn pa a si lopopona Igbara Odo si Ikẹrẹ Ekiti.
- Ààrẹ Buhari: Ìwa wèrè ni àwọn Boko Haram tó dúmbú àgbẹ̀ 40 hù
- Èèyàn 110 tún ti ní COVID-19 ní Nàìjíríà
- Olùkọ́ fipá bá akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá lòpọ̀ títí dójú ikú ní Bayelsa
- Bolu, akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tó fò ṣánlẹ̀ kù nílé ẹ̀kọ́ ni Ikorodu, Kí ló ṣekú pa á?
- Wo ohun tí Ọọ̀ni, Sultan Sokoto sọ nípa ọta ìbọn tó gbẹ̀mí Ọba Olúfọ́n
Awọn eeyan kan ni ipinlẹ Ọsun ni iranṣẹ Ọlọrun naa ti n bọ ki wọn to yinbọn pa a.
Iroyin sọ pe awọn ọmọ ijọ rẹ to reti rẹ ti wọn ko rii ko de ni Ọjọbọ to ṣeleri pe oun yoo de ni wọn kebosi sita ti wọn si bẹrẹ si ni wa a ki o to di wi pe wọn ṣawari oku rẹ ni opopona naa.
Ol.ori ijọ Onitẹbọmi (Baptist Church) ni ipinlẹ Ekiti, Ẹniọwọ Adeyinka Aribasoye ṣalaye pe ilu Ipetu Ijesha ni iranṣẹ Ọẹọrun naa ti n bọ lẹyin to lọ ki iya rẹ nibẹ.









