Tope Ajogbajesu: Mọ̀lẹ́bí kan ní orin ikú ọdún yìí fò mí ru ní Tope kọ láàrin ọ̀sẹ̀ tó kú

Àkọlé fídíò, Tope Ajogbajesu: Mọ̀lẹ́bí kan ní orin ikú ọdún yìí fò mí ru ní Tope kọ láàrin ọ̀sẹ̀ tó kú

Yoruba ni iku kii jẹ ki a dagbere fun ẹnikeji ẹni, ko to maa mu ni lọ.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu iku gbajumọ akọrin ẹmi nni, Tope Ajogbajesu, ẹni ti yoo wọ kaa ilẹ sun lonii.

BBC Yoruba se abẹwo si ile oloogbe naa, nibi ta ti ba aya rẹ, ibeji rẹ ati awọn mọlẹbi rẹ miran sọrọ lori ipa ti iku rẹ yoo ni lara wọn.

Aya oloogbe naa ni aisan ọgbẹ inu, taa mọ si Ulcer lo mu Tope ni oru Ọjọbọ, to si ku ni ọjọ Ẹti, bẹẹ lo yẹ ko gba ami ẹyẹ kan ni ọjọ Sunday.

O ni aisan ọgbẹ inu naa ti n yọ ọkọ oun lẹnu, ọjọ ti pẹ amọ oun dupẹ pe inu ifẹ Kristi ni ọkọ oun ku si, ti ko si jẹ ki Jesu bọ lọwọ oun.

Nigba toun naa n sọrọ, ikeji Tope Ajogbajesu ni oro ati ọgbẹ ọkan nla ni iku ẹnikeji oun fun oun nitori inu ifẹ nla ni awọn dijọ n gbe.

Mọlẹbi kan wa salaye pe isin kan ti Tope lọ ni ọsẹ to ku lo ti n kọrin pe iku ọdun yii fo oun ru laimọ pe ọsẹ naa ni yoo ku.