OPIC Agbara loot police arrest: Lásìkò ti àwọn mẹta yìí ń jí ọja kó ní Ado Odo Ọta lọwọ tẹ wọn- Iléesẹ ọlọpàá Ogun

Oríṣun àwòrán, The Nigeria Police, Ogun state command
Jelili Waheed, Otun Taye ati Olu Adeniran ni ọwọ àwọn agbofinro tẹ lasiko ti wọn n ko nkan nile ìkó ọja pamọ si ni Ado Odo Ọta.
Awọn agbofinro ileesẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun ti fi oju awọn ọkunrin mẹta kan hande pe ole ni wọn.
Wọn ni ọwọ tẹ awọn ọkunrin mẹta naa nigba ti wọn n ji ọja ko nile iko ọja pamọ si to jẹ tile isẹ Sky Industry Limited eyi to wa ni OPIC ni agbegbe Abara nijọba ibilẹ Ado Odo Ọta nipinlẹ Ogun.
Ileese ọlọpaa fi atẹjade sita pe Waheed Jelili to jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ati Otun Taye to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogoji pẹlu Olu Adeniran to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlaadọta ni ọwọ tẹ.
Agbenusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi lo buwọlu atẹjade naa pe lẹyin ti DPO ẹkun Agbara ri ifitonileti gab pe awọn kan n sọsẹ nibẹ lo da awọn agbofinro sita.
O ni Saleh Dahiru to jẹ ọga ọlọpaa nibẹ ni pe nkan bii ago mẹrin irọlẹ ni ọwọ tẹ awọn mẹtẹẹta yii nibẹ.
Lara awọn nkan ti wọn ri gba pada lọwọ awọn mẹtẹẹta ni ọkọ akẹru ti nọmba rẹ jẹ: AKD 747 XZ.
Okọ yii ni wọn ti fi ko awọn ẹrọ amunwa jẹnẹratọ 300KVA, 25KVA kan ati Forklift kan to jẹ ti ileesẹ Sky
Abimbọla ni kọmisọnna ọlọpaa fun ipinlẹ Ogun, Edward Awolowo Ajogun ti pasẹ pe ki wọn lọ wadii iwa awọn ti ọwọ tẹ naa ki wọn si foju ba ile ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari.
- Apostle Suleman lo ọlọ́pàá láti fi ìyà jẹ oníbàárà mi, ó fi sí àtìmọ́lé torí ọ̀rọ̀ tó sọ - Amòfin
- Èèyàn 24 nínú ẹbí kan tó lo ajílẹ̀ dípò iyọ̀ jáde láyé - kọmísọ́nà ìlera
- PDP ni yóò mú ọmọ Nàíjíríà kúrò lóko ìyà tí wọn wà ní 2023 - Kola Ologbondiyan
- Goriola Hassan, má pe ara rẹ ní ọba Imobi-Ijebu mọ́, bí bẹ́ẹ̀kọ́... - Ilé aṣòfin Ogun
- Gómìnà ìpínlẹ̀ New York ní America kọ̀wé fipò sílẹ̀!















