Òfin tí yóò mú àtúnṣe bá ìlànà ìsìnkú ọba ní ìpínlẹ̀ Ògùn ń bọ̀ lọ́nà

Aworan Gomina Abiodun ati Alake ilu Ẹgba

Oríṣun àwòrán, Twitter/dabiodunMFR

Abadofin ti yoo mu atunto ba ilana isinku awọn lọbalọba ni ipinlẹ Ogun ko ni pe dofin.

Nile aṣofin ti wọn ti n ṣe ijiroro lori ofin naa, awọn aṣofin ti ka abadofin naa ni igba ẹlẹẹkeji.

Ohun ti ofin naa n gbero ni lati jẹ ki awọn ọba to ba waja ni anfaani isinku ni ilana ẹsin to wu wọn yala ti Kristẹni tabi ti Islam.

Ofin yi ti wọn pe orukọ rẹ ni 'Ogun State Traditional Rulers (Installation and Burial Rites) Bill 2020' ṣebi ẹni ri atẹwọgba lọdọ awọn aṣofin naa.

Ninu ọrọ tirẹ, aṣoju Balogun Akeem Agbolade to jẹ agbatẹru aba naa ni ofin ọhun ṣe pataki lati dena awọn aṣa ti koba igba mu nipa sisin awọn ọba tabi nipa awọn eto ifinijoye wọn.

Olori ile ni tiẹ sọ pe o di dandan lati daabo bo awọn lọbalọba lọwọ awọn aṣa to tabuku ba ijẹọmọniyan .

Lọpọ aaye ni awọn ilana isinku ti wọn a ma ṣe ni bonkẹlẹ ti gbode kan.

Ninu awọn aṣa isinku lati gbọ pe awọn kan a ma ni ki wọn sin eeyan pẹlu ọba to ba ku iyẹn ta mọ si abọbaku.

Oluwo gboṣuba fofin ilana isinku Ogun.

Oluwo ilu Iwo nipinlẹ Osun tio gboṣuba kare fawọn aṣofin ipinlẹ Ogun pẹlu igbesẹ wọn eleyi ti yoo mu atunto ba ilana isinku awọn Ọba lagbegbe wọn.

Oba Abdulrasheed Akanbi kan saara si Awujale ilu Ijẹbu Ọba Sikiru Adetona pe iru idagbasoke yi n waye lasiko rẹ lori apere.

Àkọlé fídíò, Olúwòó ní àwọn Ọba ń se ẹgbẹ́ òkùnkùn

Ti ofin yi ba kẹsẹjari,eyikeyi Ọba to ba ku yoo ni anfaani isinku ni ilana ẹsin to ba yan laayo yatọ si aṣa tẹlẹ pe wọn yoo sin nilana iṣẹmbaye.