COVID19Nigeria: Èèyàn mẹ́rin kú, 747 míràn tún lùgbàdì aàrùn náà ní Nàìjíria

Afihan oṣiṣẹ ilera to n ṣe ayẹwo fun Covid-19

Oríṣun àwòrán, NCDC

Aarun Coronavirus tun ti mu ẹmi eeyan mẹrin miran lọ ni Naijiria.

Gẹgẹ bi ọrọ ti ajọ NCDC fi lede loju opo wn ni Facebook lalẹ Ọjọru, eeyan 747 tuntun miran lo tun fara kasa arun ọhun bayii.

Esi yii ti sọ apapọ awon to ti ko arun naa ni Naijiria lapapọ di 176,011, awọn 165,208 ti ri iwosan nigba ti awọn 2,167 si ti dero ọrun.

Ẹda tuntun aarun naa kan ti wọn pe orukọ r ni DeltaVariant ni ijọba ti kilọ pe ki araalu ṣọra fun.

Bi iye awọn eeyan to ṣẹṣẹ ko arun naa kaakiri Naijiria ṣe lọ ree:

Lagos-488

Akwa Ibom-121

Oyo-29

Rivers-25

Ogun-15

FCT -13

Kaduna-13

Kwara-11

Ekiti-10

Osun-10

Edo-6

Abia-3

Anambra-2

Plateau-1

Ipinlẹ mẹrin ni wọn ko ti ri eeyan kankan to ko aarun naa-Sokoto,Nasarawa,Kano ati Ondo.

Aworan afihan iye eeyan to lugbadi Covid-19

Oríṣun àwòrán, NCDC