Gastroenteritis Outbreak: Kí ló dé tí ìgbẹ́ gbùùrù àti inú ríru fi ń dá ọlọ́kadà àti 'mai-bola' láàmú ní Ogun?

Aworan akodọti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba ipinlẹ Ogun ti kede ajakalẹ kokoro aifojuri kan to n daamu awọn ọlọkada ati awọn to n ṣalẹ ni ipinlẹ naa.

Niṣe ni aisan yi to maa n farahan nipa igbẹ gbuuru ati inu rirun gbode lagbegbe Magboro, Ofada ni ijọba ibilẹ Obafemi Owode.

Ileeṣẹ ilera fidi ọrọ yi mulẹ ninu atẹjade kan ti Kọmisana feto ilera Tomi Coker fi sita .

Wọn sọ pe awọn to ko aisan yi a maa saba ya igbe gbuuru, inu a maa run wọn, koda ẹlomii a maa bi pẹlu.

Tomi Coker ṣalaye pe ẹni tawọn fura si pe o ko aisan yi wọle ṣẹṣẹ dari pada si ipinlẹ naa.

Kọmiṣana yi ṣalaye pe ile igbọnsẹ lawọn to n ko aisan yi ti n saba lugbadi rẹ ati pe awọn ọlọkada ati awọn to n ṣa ilẹ lo pọ ninu awọn to lugbadi rẹ.

Aworan Olokada

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile igbọnsẹ ti wọn lawọn fura si pe itankalẹ aisan yi ti bẹrẹ ti wa ni titi pa gẹgẹ bi Kọmisana ṣe ṣalaye.

Lọwọlọwọ o ni awọn to lugbadi aisan naa n gba itọju nile iwosan lati le dẹkun itankalẹ aisan yi.

O ni awọn ko ti le ṣe ayẹwo omi ara itọ tabi igbẹ awọn to ko aarun naa nitori awọn ko ni eeyan kankan to n koju aisan yi lọwọ bayi.

Ẹwẹ Kọmisana naa sọ pe awọn ile iwosan gbarọgudu kan ti da kun itankalẹ aisan yi nipa bi wọn ṣe n ṣe itọju awọn eeyan.

O ni ijọba ti ṣe idasilẹ awọn aaye itọju si ile iwosan to wa ni Magboro-Akeran tawọn si ti pese ohun eelo itọju sibẹ.

Awọn onimọ sọ pe iru aarun yi a maa tan ka nipa omi tabi ounjẹ to ba ni kokoro aifoujri gastroentritis ninu.

O lewu fawọn agbalagba to ba ni ipenija lara ati awọn ọmọ ikoko.