Kazeem Tiamiyu: Wọ́n ti sin òkú agbábọ́ọ̀lù Remo Stars tí wọ́n sọ pé SARS pa ní Sagamu

Kazeem Taimiyu ni igbakeji balogun ẹgbẹ agbabọọlu Remo Stars nigba aye rẹ

Oríṣun àwòrán, Twitter/remo stars sports club

Àkọlé àwòrán, Kazeem Taimiyu ni igbakeji balogun ẹgbẹ agbabọọlu Remo Stars nigba aye rẹ

Wọn ti sin oku agbabọọlu, Kazeem Tiamiyu, ti iṣẹlẹ iku rẹ fa iwọde nilu Sagamu nipinlẹ Ogun, ṣugbọn awọn ibeere kan ṣi n jẹyọ lori iku to pa a.

Ẹni ọdun mọkanlelogun ọhun, to n gba bọọlu fun Remo Stars, ni ọkọ gba, to si gba ibẹ ku, ṣugbọn ẹgbẹ agbabọọlu rẹ sọ pe awọn ọlọpaa lo pa a.

Ọrẹ rẹ kan naa to sọ pe iṣẹlẹ naa ṣoju ohun naa sọ fun BBC pe awọn ọlọpaa SARS lo ṣokunfa iku rẹ.

Àkọlé fídíò, Saani: Gbogbo egungun Tiamiyu ló kán lẹ́yìn tí wọ́n tì í jábọ́ nínú ọkọ̀

Nibi eto isinku na to waye ni Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ni awọn ẹbi, ọrẹ ati akẹẹgbẹ rẹ ti kopa, wọn si wọ Tiamiyu ni aṣọ funfun, ti wọn si sin ni ilana ẹsin Islam.

Agboole ẹbi rẹ to wa ni Ajaka nilu Sagamu nipinlẹ Ogun ni wọn sin si.

Ṣe ko si obi to gbadura lati f'oju sunkun ọmọ, ẹ gbọ nkan ti awọn obi oloogbe Tiamiyu ba BBC Yoruba sọrọ nipa rẹ.

Àkọlé fídíò, 'Mo fẹ́ ìdájọ́ òtítọ́ àti òdodo lóríi ikú àìmọ̀dí tí wọ́n fi pa ọmọ mi'

Aarẹ ẹgbẹ agbabọọlu Remo Stars, Kunle Soname, ati Aarẹ ajọ to n mojuto bọọlu gbigba ni Naijiria, NFF, Amaju Pinnick naa ti lọ ba ẹbi oloogbe kẹdun l'ọsẹ yii.

Jakejado Naijiria ni awọn eniyan ti koro oju si iru iku to pa Tiamiyu, nitori bi iroyin ṣe sọ pe lasiko ti awọn ọlọpaa SARS da a duro sinu ọkọ wọn lo pade iku ojiji.

Eyi si mu ki ọpọlọpọ olugbe ilu Sagamu ṣe iwọde, ti awọn eniyan fi n beere fun idajọ ati ipolongo pe ki wọn o pa ẹka ọlọpaa SARS rẹ.

Eniyan mẹta si ni iroyin tun sọ pe o padanu ẹmi wọn nibi iwọde naa, ti awọn ọlọpaa si sọ pe awọn ṣi n ṣe iwadii awọn ẹsun yii.

Aworan awọn oluwọde

Oríṣun àwòrán, Twitter/Ekwulu

Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ olugbe ilu Sagamu lo kopa nibi iwọde naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọlọpaa to lọwọ si iṣẹlẹ naa ti wa ni ihamọ, ati pe wọn ti gbe e lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ti n ṣewadi iwa ọdaran.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba sọ fun BBC pe "iwadii ṣi n lọ lọwọ, ileri wa si awọn ọmọ Naijiria si ni pe a ko ni ṣe mago-mago tabi fi ohunkohun pams nipa iwadii naa".