Lagos: Àwọn olùgbé Kosofẹ́ figbe ta pé iná, bátírì, dígí, àti ẹ́ńjínì ọkọ̀ láwọn olè ń jí gbé lóru

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn olugbe agbeegbe Kosofe ni ijọba ibile Agboyi-Ketu ti ke sijọba ipinlẹ Eko lori iṣekupani to n waye ni gbogbo igba ni agbeegbe naa.
Awọn olugbe naa ni awọn ole ma n ba mọto awọn jẹ, ti wọn a si tu ẹya ara rẹ lọ.
Lara awọn to faragba ninu iṣẹlẹ naa sọ fun awọn oniroyin pe, awọn adigunjale naa ma n wọ asọ bi awọn ẹsọ alaabo to n kaakiri ni agbeegbe naa, ti wọn yoo fi raye wọle si agbeegbe yii lati ṣọṣẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ! Agbowu pe Oluwo l'ẹ́jọ̀, ó ń bèèrè ₦100m owó gbà má bínú
- Làá hàn mí dé, ètò tó ń ṣàlàyé ohun tó yẹ ká ṣe láti dènà àrùn Coronavirus
- Àrùn Coronavirus ti tàn dé orílẹ̀-èdè míràn nílẹ̀ Afrika
- Pa Kasumu tó ni ohùn ló lọ,ohùn tó fi sílẹ̀ kò ní parẹ́
- Pa Kasumu: Lere Paimo ní àìrìríjẹ́, àìrímú tàbí ìrònú má a ń jẹ́ kí ọjọ́ ogbó dagun
Lara awọn agbeegbe ti ọrọ naa kan ni Agbeegbe Iyanse, Onagoruwa, Kosofe ati Iyana School bus stop, tawọ̀n eeyan agbegbe naa si ni wọn maa n gba ohun ini awọn.
Wọn tiẹ fikun wi pe, awọn aidgunjale yii ti ji ẹya ara ọkọ to le ni mẹtala ni agbeegbe naa.

Oríṣun àwòrán, Others
Bẹẹ ni wọn kesi ijọba lati bojuto awọn eto aabo to dẹnukọlẹ ni awọn agbeegbe ti awọn adigunjale yii ti n ja ran-in.
Arakunrin Tony, to ni wọn ba ọkọ SUV oun jẹ ni aago meji oru, ti wọn si ṣi bonnet ọkọ, ki wọn to fi ipa ṣi ferese ọkọ, ti wọn si raye wọle.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin eyi lo ni wọn yọ engine ọkọ, ina ọkọ, batiri ọkọ, jigi ẹgbẹ ọkọ ko to di wi pe wọn wa ọkọ ti wọn jade, lẹyin ti wọn ti yọ gbogbo ohun ti wọn fẹ́ yọ tan.
- Gómìnà Oyetọla tí yi ìlànà ètò ẹ̀kọ Rauf Aregbesola pada
- Obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ ẹrú ní Oman tó bá fẹ́ òmìnira, yóò bá ọ̀gá rẹ̀ ṣùn - obìnrin méjì tó ti oko ẹrú dé
- A dúpẹ́ o! Lẹ́yìn àyẹ̀wò, kò sí alárùn Coronavirus ní Nàíjíríà, sáká lara wa dá - Mínísítà
- "Àbámọ̀ ló gbẹ̀yìn bí mo ṣe yípadà láti obìnrin sí ọkùnrin, ń kò bá tí ṣe bẹ́ẹ̀"
Tony ni o le ni ọgbọn iṣẹju ti awọn onisẹ laabi naa fi sọṣẹ ni agbeegbe awọn, ti ko si si oluranlọwọ kankan fun awọn.
Nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa fesi, wọn ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye ti awọn si ti bẹrẹ̀ iwadii ni pẹrẹwu lati mu awọn adigunjale naa.












