Coronavirus: Ọmọ orílẹ̀-èdè France kan ti kó àrùn Coronavirus wọ Senegal

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Minista eto ilera orilẹ-ede Senegal, Diouf Sarr ti sọ pe arun Coronavirus ti tan de orilẹ-ede naa.

Diouf ni okunrin ọmọ orilẹ-ede France kan to n fi Senegal ṣebugbe lo ko arun naa wọle lẹyin to ṣabẹwo si orilẹ-ede rẹ lọsu Keji.

Okunrin naa pada si Senegal lọjọru to kọja, to si ṣabẹwo si ile iwosan kan lẹyin to ṣaisan rampẹ, ṣugbọn ile iwosan ọhun si fi ọrọ naa to ileeṣẹ eto ilera leti latari ibẹru arunb Coronavirus.

Lọwọ yii, okunrin ọhun ti wa ni apaọ nile iwosan nibi to ti n gba gba itọju.

Ṣugbọn ijọba Senegal ti bẹrẹ si n wa awọn eeyan ti wọn jọ wọ ọkọ baalu kan naa lati France si Senegal.

Orilẹ-ede Senegal ni orilẹ-ede keji ni iha isale asale Sahara ti arun naa ti wọ bayii lẹyin Naijiria.

Macky Sall

Oríṣun àwòrán, @Macky_Sall

Aarẹ ilẹ Senegal, Macky Sall ti rọ awọn eeyan orilẹ-ede naa lati ma gba ibẹru kankan laye ninu ọkan nitori iṣẹlẹ ọhun.

O ni ijọba oun yoo sa ipa rẹ lati ri pe arun naa ko di tọrọ kọbọ lorilẹ-ede ọhun.

Àkọlé fídíò, Oman Returnees: Ọ̀kan lára àwọn obìnrin méjì náà ní òun ṣiṣẹ́ ọdún kan láì mú ₦5 padà wálé