Amotekun: Àwọn aṣòfin Yorùbá ní ikọ̀ aláàbò náà yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́sẹ̀ díẹ̀ s‘ásìkò yìí

Ọjọ Iṣẹgun ni abadofin ikọ Amọtẹkun kẹsẹjari kaakiri gbogbo ipinlẹ to wa ni ẹkun iwo oorun Naijiria lẹyin ti awọn ile asofin ni awọn ipinlẹ mẹfẹẹfa buwọlu.
Bakan naa ni wọn n reti ki awọn gomina ipinlẹ koowa wọn, ki wọn buwọlu ofin naa fun lilo.
Olori ile asofin ni ipinlẹ Oyo, Adebo Ogundoyin nigba to n sọrọ lori ofin naa ni, ikọ amọtẹkun yoo bẹrẹ iṣẹ lẹyin ọṣẹ diẹ si akoko yii, tawọn gomina ba sọ di ofin.
Ogundoyin ni ikọ amọtẹkun naa yóò wá fún ìṣàkóso ètò ààbò ní àwọn ìpínlẹ̀ kọ́ọ̀kan tó wà ní ìlẹ̀ Yoruba ti ètò ààbò ti dẹnukọlẹ̀.
Olotu eto idajọ ni ipinlẹ Ondo ati kọmisọnna fun eto idajọ, Kola Olawoye ni igba akọkọ niyii, ti gbọgbọ ilẹ Yoruba yoo fi imọ sọkan lori itẹsiwaju awujọ wọn, lai si alatako laarin wọn.

Ogun:
Ọjọ kọkandinlogun ti ile igbimọ asofin ipinlẹ Ogun bẹrẹ asaro lori ikọ abadofin amọtẹkun ni wọn buwọlu.
Awọn asofin naa ni bi awọn ṣe yara si abadofin naa fihan gbangba wi pe awọn ṣetan lati rẹyin iwa ọdaran ati iṣekupani to n waye ni agbeegbe naa.
Eko:
Ọjọ Iṣẹgun ni ipinlẹ Eko sọ abadofin ikọ amọtẹkun di ofin gẹgẹ bi ọkan lara ikọ to n boju eto aabo ni ipinlẹ Eko, labẹ ofin Lagos State Neighborhood Safety Corps Agency Law, 2019.
Ni ipinlẹ Eko, ikọ amọtẹkun ko le e ṣiṣẹ fun awọn oloṣẹlu, bẹẹ ni wọn ko le ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọlọpaa ni ipinlẹ ọhun.
Ipinlẹ Ondo:
Ni ọjọ kejidinlogun, osu keji ọdun 2020 ni ipinlẹ Ondo buwọlu abadofin naa.
Abẹnugan ile igbimọ asofin naa, to wọ aṣọ amọtẹkun sọ wi pe ni kete ti gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ba ti buwọlu abadofin naa, ni iwa ọdaran yoo dẹkun ni ipinlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Postsubman
Osun:
Ilu Osogbo ni awọn aṣofin naa ti buwọlu abadofin ikọ amọtẹkun nipinlẹ Osun, bi o tilẹ jẹ pe o ni awọn atunṣe ti wọn ṣe nipa rẹ fun igba diẹ laarin igbimọ to gbe kalẹ ati abajade abadofin naa.
Abẹnugan ile asofin naa wa dupẹ lọwọ awọn aṣofin naa fun bi wọn ṣe parapọ lati tete buwọlu abadofin naa.












