Shonekan dies: Adarí ìjọba fìdíhẹ Naijiria tẹ́lẹ̀ Ernest Shonekan fi ayé sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, @NijaEye
Oloye Ernest Shonekan to jẹ olori ijọba fidihẹ Naijiria lẹyin ijọba Ọgagun Ibrahim Babangida ti jẹ ọlọrun nipe.
Shonekan to jẹ ogunna gbongbo ti n datọ lẹnu igbin nidi idari awọn ile iṣẹ ṣaaju yiyan rẹ gẹgẹ bii Aarẹ fidihẹ jade laye nilu Eko lọmọ ọdun marundinlaadọrun.
Shonekan jẹ Alaga Ijọba fidiẹ Naijiria laarin ọjọ kérinbdilogun, oṣu Kẹjọ, si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 1993.
- Irọ́ ńlá! kò sí "Hacker" kankan ò kọlu ẹ̀rọ ayélujára wa o, nọ́mbà yín wà ní ṣẹpẹ́ - Àjọ NIMC
- Afọbajẹ tí mò ń ṣe látọdún yìí ti tó, ẹ jẹ́ kí èmi náà dádé Ààrẹ - Tinubu
- Ìgbà márùn ùn ọtọ́ọ̀tọ tí Nàìjíríà àti Egypt kojú lórí pápá ní Afcon
- "A ò lè sọ pàtó ibi tí Raheem Adedoyin wà báyìí"; "Àmọ́ ẹ mọ̀ nígbà tí ọlọ́pàá kò tíì wá a"- Agbẹjọ́rò Adedoyin àti ti ìdílé Timothy takurọ̀sọ
- Kìí ṣe ilẹ̀ Afíríkà ni mo wà nígbà tí mo kọ́kọ́ wá sílé ayé - àṣírí ọ̀rọ̀ tuntun rèé lẹ́nu Mummy G.O
- Wo bí ọ̀fìnkìn ṣe lè dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ àrùn Covid-19
Ọdun kan naa ni ọgagun Sani Abacha yẹ aga ijọba nidi rẹ.
Oloogbe naa kékọọ gboye imọ ofin nilẹ Gẹẹsi, o tun jẹ oniṣowo to yanranti.
Shonekan ni ọga agba ileeṣẹ United African Company of Nigeria Plc, UAC, ki ọgagun Ibrahim Babangida to yan gẹgẹ bii Aarẹ fidihẹ lọdun 1993.
Wọn bi Shonekan lọjọ kẹsan an, ọsu Karun un, ọdun 1936 niluu Eko.
O kawe ni ile ẹkọ CMS grammar school niluu Eko ati Igbobi College, ko to tẹsiwaju kẹkọgboye ni fasiti ilu London ati Harvard Business School.














