Afe Babalola: Adarí Nàíjíríà kankan kò leè ṣàṣeyọrí pẹ̀lú òfin ọdún 1999

Oríṣun àwòrán, @hartarmah1
Agba amofin nni, Afẹ Babalọla ti kede pe ofin ti orilẹede Naijiria n lo lọwọlọwọ bayii ko kun to, to si mẹhẹ lati yanju oniruuru isoro to n ba orilẹede yii finra.
Ilu Ado Ekiti ni Afẹ Babalọla ti woye ọrọ yii lasiko ti ajọ isọkan ilẹ Afirika n fi oye Awokọse rere nilẹ Afirika da lọla.
Babalọla ni ofin ilẹ wa tọdun 1999 jẹ adina fun eto idagbasoke ati ilọsiwaju Naijiria taa ba wo ọpọ kudiẹ-kudiẹ to wa ninu amulo ati amusẹ rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O ni yoo nira pupọ, ti yoo si jẹ isoro nla fun eyikeyi adari orilẹede Naijiria lati se aseye ti alakan n se epo lori aleefa, ta ba si n lo ofin naa, pẹlu afikun pe ofin ọdun 199 kogbewọn to fun irufẹ akanda orilẹede ti Naijiria jẹ.
Babalọla ni ayafi ti a ba gbe igbesẹ akin lati mu ayipada ba ofin ọdun 1999 naa, se ni ọps aayan wa lati se aseyọri yoo maa ja si asan.

Oríṣun àwòrán, @hartarmah1
Bakan naa ni agba amofin yii tun woye pe, ba se n pe ofin ilẹ wa naa ni 'ofin apapọ Naijiria' jẹ eyi ti ko bojumu to, nitori ofin to wa fun igun kan ni.
- Ọkọ̀ akẹ́rù Dangote rọ́lu BRT lọ́nà Ikorodu, èèyàn kan kú, 59 farapa, ẹsẹ̀ dẹ́rẹ́bà gé
- Àwọn ọmọ Nàíjíríà ló ṣiṣẹ́ takò mí ní Ireland kí ń má baà wọlé ìbò Káńsélọ̀ - Yemi Adenuga
- Láti January lọ, gbogbo ẹni tó bá ra ọjà lórí ayélujára yóò máa sanwó orí - FIRS
- Aṣojú Seyí Makinde lásan ní mo jẹ, òṣìṣẹ́ gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún mi - Ọ̀dọ́mọdé Kọmísánà
Afẹ Babalọla wa rọ aarẹ Muhammadu Buhari lati pe ipade apero apapọ awọn ọmọ Naijiria, ta si mu awọn asoju lai lo ẹgbẹ oselu kankan.
O ni nibi ipade yii ni wọn yoo ti gbe ofin kalẹ fun Naijiria eyi ti yoo foju sun idagbasoke awọn ọmọ orilẹede yii.












