SW Security: Ìpàdé ààbò wáyé nílẹ̀ Yorùbá, wọ́n fẹnu ọ̀rọ̀ jóná pẹ̀lú ilééṣẹ́ ọlọ́pàá

Ọga agba Ọlọpaa ati Gomina Seyi Makinde n sọrọ

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Eto aabo to n fori sanpọn nilẹ Yoruba ti wa di irawọ ọsan to n bawọn agba lẹru bayii.

Eyi si lo mu ki ọga agba ọlọpa nilẹ wa, Mohammadu Adamu fi fi ilu Abuja silẹ, wa se ipade pẹlu awọn gomina atawọn eeyan ti eto aabo gberu lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.

Ninu ipade apero mii to tun waye lọjọ Aje lori ifẹsẹmulẹ eto aabo to peye lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, ni wọn ti sisọ loju rẹ faraye pe ẹgbẹ akọya nilẹ Yoruba, OPC tii fi ẹnu ọrọ jona pẹlu ileesẹ ọlọpa ilẹ wa, lati ja ogun eto aabo to mẹhẹ naa nilẹ Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gomina Seyi Makinde, to n gbalejo ipade ọhun, ninu ọrọ rẹ, tun sisọ loju rẹ pe awọn gomina ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria ti setan lati tun se amulo awọn irinsẹ igbalode feto aabo lati mu ki aifararọ aabo ọhun tẹriba.

Ọọni Ifẹ n ki Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

O ni amulo ẹrọ ayaworan CCTV ni yoo fẹsẹ mulẹ, eyi ti yoo mu adinku ba eto aabo to n ba ilẹ Yoruba finra naa, ti yoo fi di afiẹyin ti eegun fi asọ.

Ko tan sibẹ, awọn gomina ilẹ Yoruba naa tun fori okoo sọdun pẹlu ọga ọlọpaa nilẹ wa naa, lati gba awọn osisẹ ọlọpa ẹlẹkunjẹkun lati agbegbe kọọkan ti wọn tẹdo si.

Afojusun eyi ni Makinde sọ pe yoo mu ki awọn osisẹ ọlọpa agbegbe naa maa sugba awọn osisẹ agbofinro yoku nipa mimu adinku ba eto aabo.

Olubadan n ki Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Bakan naa ni Makinde sọ pe " A ti fẹnu ọrọ jona pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ akọya ilẹ Yoruba, OPC, Miyetti Allah, tii se ẹgbẹ awọn darandaran ati awọn osisẹ agbofinro yoku wa ninu igbimọ eleto aabo kan ti yoo wa fun ipinlẹ mẹfẹẹfa nilẹ Yoruba, lati wa ọna ti adinku yoo fi ba eto aabo to mẹhẹ."

Ko tan sibẹ o, Makinde tun sisọ loju rẹ pe, ọga agba ọlọpa ti fọwọ si idasilẹ akanse igbimọ amusẹya kan ti kọmisana ọlọpa kan yoo ko sodi, eyi ti yoo tete pa ina eto aabo to mẹhẹ, eyi to n jo yika ilẹ Yoruba.

Oba ilu Eko, Olubadan ati Ọọni n ki Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Lara awọn eeyan mii to peju sibi ipade naa ni awọn gomina lati awọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba, awọn ileesẹ agbofinro lorisirisi, awọn ọba alaye nilẹ Yoruba ninu eyi ta ti ri Olubadan ati Ọọni tilu Ile Ifẹ, awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lawujọ, awọn asaaju ẹsin ati awọn asaaju awujọ.