Seyi Makinde: Inú mi dùn láti rí àwọn ìjòyè lẹ́yìn Olúbàdàn

Olubadan ati awọn agba ijoye nilẹ́ Ibadan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Yooba ni ka rin, ka pọ, yiyẹ nii yẹ ni, bẹẹ si ni apọnle ko si fun ọba to da lọ sode.

Idi ree ti ori gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde fi n fo fun ayọ, to si ni ori oun wu pupọ lati awọn agba ijoye ilẹ Ibadan ti wọn kọwọ rin pẹlu Olubadan ilẹ ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunnisọ Kinni.

Gomina Makinde, ẹni to woye ọrọ yii lasiko to n side ipade apero lori eto aabo to waye nilu Ibadan lọjọ Aje, wa kan saara, to si se sadankata si Olubadan ati awọn agba ijoye nilẹ Ibadanlori bi wọn se jẹ ki ogun sinmi, ti wọn si gba alaafia laaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn agba ijoye naa, ti wọn tẹle owe Yoruba to ni ọba meji kii wa ni aafin, bi o tilẹ jẹ pe ijoye lee pe mẹfa laafin, ni wọn de fila lasan ati ilẹkẹ sọrun lai de ade sori, to si jẹ pe Olubadan nikan ni ade wa lori rẹ.

Olubadan n ki Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Ijoko Olubadan naa ati awọn ijoye rẹ to wu oju ri, to si jẹ pe oju gbogbo n wo wọn nibi ipade apero ọhun, lo mu ki gomina Makinde ni "inu mi dun lati ri awọn ijoye ti wọn kọwọ rin pẹlu Olubadan wa sibi."

Ọrọ yii lo mu ki awọn eeyan bu sẹrin ayọ, ti wọn si patẹwọ, bẹẹ ni wọn n juwọ si ibi Olubadan ati awọn ijoye rẹ naa joko si.

Bẹẹ ba gbagbe , o ti to ọdun meji ti Olubadan ati awọn agba ijoye nilẹ Ibadan ti dijọ jade sita gbangba papọ bayii, eyi ko si sẹyin wahala to waye nitori bi ijọba ana nipinlẹ Ọyọ se de ade fun awọn agba ijoye mọkanlelogun nilẹ Ibadan.

Lara awọn agba ijoye to kọwọrin pẹlu Olubadan ni Ọtun Olubadan, Agba oye Lekan Balogun, Agba oye Owolabi Ọlakulẹyin, Asipa Olubadan Eddy Oyewọle, Asipa Balogun Olubadan, agba oye Lateef Adebimpe, Ẹkarun Olubadan, agba oye Amidu Ajibade ati Ẹkarun Balogun Olubadan, agba oye Kọla Adegbọla.