Ajao Estate Gas Explosion: Alága ìjọba ìbílẹ̀ Isolo ní àwọn yóò fi òfin dè títà afẹ́fẹ́ gáàsì létílé

Ibugbamu Gaasi ni Ajao Estate

Ijọba ipinlẹ Eko ti ni awọn yoo ṣe agbeyẹwo ofin ti yoo dena ki awọn eeyan maa ta afẹfẹ gaasi lẹba ibi ti awọn eeyan n gbe.

Ọrọ yi waye lataari ibugbamu afẹfẹ gaasi to ṣe akoba fun dukia ati ẹmi awọn eeyan ni adugbo Ajao Estate ni ilu Eko.

Alaga ijọba ibilẹ Isolo, Shamsudeen Abiodun Olaleye lo fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC lasiko to ṣe abẹwo si ibi ti ijamba naa ti waye.

Olaleye ni lootọ ni pe koṣeemani ni lilo gaasi f'awọn ara ilu ṣugbọn ohun to ṣẹlẹ yi ti sọ di dandan ki ijọba mu opin ba tita afẹfẹ gaasi lẹgbẹ ibugbe awọn eeyan.

''Ohun to jẹ wa logun kii ṣe awọn to n pa owo nidi tita gaasi, bi ko ṣe didaabo bo ẹmi wọn ati ti awọn eeyan to rọgba yika wọn.''

O ni ijọba yoo gbe igbesẹ lati ri i wi pe iru nkan bayii ko tun waye mọ.

Bakan naa ni aṣoju ẹkun idibo Oshodi/Isolo, Jude Idimogu to kọwọrin pẹlu Alaga naa ni awọn yoo wo ilana ti yoo mojuto bi wọn ko ṣe ni maa ta afẹfẹ gaasi ni itosi ile ibugbe jakejado ipinlẹ Eko.

Ibugbamu Gaasi ni Ajao Estate

Ki lo ti ṣelẹ sẹyin?

Ọ̀pọ̀ òkú ṣùn, dúkìá jóná nínú àkọ̀tun ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù gáàsì l'Eko

Ọrọ ibugbamu to n fi ojoojumọ waye nipinlẹ Eko bayii ti wa di ailasọ lọrun paaka bayii, eyi to to apero fun gbogbo ọmọ eriwo.

Idi ni pe isẹlẹ ibugbamu miran tun ti waye nilu Eko lọjọ Isẹgun ninu ibudo itaja kan ti wọn ti n ta afẹfẹ gaasi ati eroja Kanbaadi.

Ajọ to n ri si akoso isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA to fidi rẹ mulẹ loju opo Twitter rẹ, salaye pe opopona Afariogun ladugbo Ajao Estate nilu Eko ni isẹlẹ naa ti waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasema ni ibugbamu Kanbaadi ati afẹfẹ gaasi papọ yii si lo se okunfa ijamba ina alagbara kan ninu ile itaja naa.

Awọn osisẹ ajọ Lasema n sisẹ nibi ti ibugbamu ti waye

Oríṣun àwòrán, @followlasema

Ileesẹ o kere tan, ibudo itaja mẹsan miran lo fara gba ninu isẹlẹ ọhun, tii wọn si jona kanlẹ.

Ileesẹ to n se akoso awsn isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko ni ifọwọsowọpọ isẹ ajọ panapana nipinlẹ Eko ati ajọ naa lo mu ki wọn tete bu omi pa ijamba ina naa.

Awọn osisẹ ajọ Lasema n sisẹ nibi ti ibugbamu ti waye

Oríṣun àwòrán, @followlasema

Ọpọ eroja bii ọpa, silinda gaasi ati awọn nnkan miran to ti jona ni wọn ri nibi isẹlẹ naa, ti ajọ Lasema ko si sọ boya ẹmi kankan sọnu ninu ijamba naa.