Ijegun Fire: Ẹ̀mí méjì, ọgbọ̀n ọkọ̀ àti ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ́bù ló bá ìjàmbá iná rìn

Oru Ọjọbọ ni ibugbamu ina waye ni adugbo Ijẹgun ni Eko, tileesẹ NNPC si kede pe awọn eeyan to n ji epo wa lo ṣe okunfa rẹ.

Ina ati eefin dudu to n jo lọ soju ọrun
Àkọlé àwòrán, Ina ọmọ ọrara. Ina lo n jo soke yii, ti oju ọrun dudu lai rọ ojo. Rẹrẹ run
Awọn osisẹ panapana n sisẹ lati pa ina to n jo ati mọto to n jona
Àkọlé àwòrán, Isẹ kekere kọ ni awọn panapana se lati ka ọwọja ina ọhun ko, kekere kọ. Ọ́pọ mọto to bajẹ ree, ofo nla se
Awọn osisẹ panapana n sisẹ lati pa ina to n jo ati mọto to n jona
Àkọlé àwòrán, Bi epo pẹtroolu se wulo to, idakeji rẹ yii wa n kọ,? O buru jai to ba foju kan ina
Awọn osisẹ panapana n sisẹ lati pa ina to n jo ati mọto to n jona
Àkọlé àwòrán, Bi eeyan jẹ ori ahun, yoo kawọ leri to ba de ibi ti ijamba ina ti waye ni Ijẹgun
Awọn osisẹ panapana n sisẹ lati pa ina to n jo
Àkọlé àwòrán, Ẹ ku isẹ o, Ọba oke yoo maa ran yin lọwọ. Ẹgan ni ẹ, awọn panapana se isẹ. Ori mọto wọn ni wọn tun gun lọ yii
Awọn osisẹ panapana n sisẹ lati pa ina to n jo
Àkọlé àwòrán, Ki la ti fẹ se awọn ijamba ina epo pẹtiroolu to maa n waye ladugbo Ijẹgun, nipinlẹ Eko yii si
Awọn osisẹ panapana n sisẹ lati pa ina to n jo , ti ọpọ ero si pejọ ti wọn
Àkọlé àwòrán, A ba awọn mọlẹbi awọn eeyan to fori sọta ijamba ina to waye ni Ijẹgun yii kẹdun pẹlu awọn eeyan ti ọkọ ati isọ wọn jona