Muhammadu Buhari: APC ẹ ṣọ́ra, ẹgbẹ́ kò gbọdọ̀ túká lẹ́yìn ìsàkóso mi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Prof Yemi Osinbajo
Ko si ohun to jọọ rara! Aarẹ Muhammadu Buhari soju abẹ niko lori iroyin kan to n tan kalẹ pe aarẹ n gbero lati lọ fun saa kẹta, ti saa keji rẹ ba pari.
Aarẹ Buhari sọ pe, oun ko ni ṣe aṣiṣe lati gbegba ibo aarẹ fun saa kẹta gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria.
Buhari sọrọ yii mimọ nibi ipade igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ osẹlu APC to waye niluu Abuja lọjọ Ẹti.
- Ọ̀nà kan ò wọjà fáwọn òṣèré tíátà, bí wọn ṣe ń ta ìpara ìbóra ni wọ́n ń ta aṣọ ẹbí
- Ṣowore, Bakare gbé ọga DSS lọ sílé ẹjọ́, bèèrè fún bílíọ̀nù kan náírà
- Mo bọ́ lọ́wọ́ igbó mímu ṣùgbọ́n ìnira ilé Aafa Ọlọrẹ ti pọ̀jù- ọ̀dọ́ kan
- A jọ ṣe ìyàwó pọ̀, a jọ bímọ ní ọjọ́ kan náà, a tún jọ máa ń ṣàìsàn pọ̀ ni
- Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn
- Àgbẹdọ̀! Má kọ̀wé fipò sílẹ̀, àwọn àgbààgbà Yorùbá sọ fún Osinbajo
- Àráàlú yarí fún fásitì Babcock fún bo ṣe lé akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn bá lòpọ̀ nínú fídíò
Aarẹ Buhari ni yatọ si ọjọ ori oun, o ni oun ti bura pẹlu iwe mimọ pe oun ko ni ṣe ohun kohun to lodi si iwe ofin orilẹede Naijiria.
Buhari ni saa meji ti iwe ofin ilẹ Naijiria la kalẹ fun ipo aarẹ naa loun yoo ṣe.
Aarẹ wa kilọ fawọn ọmọ ẹgbẹ osẹlu APC nibi ipade ọhun pe ẹgbẹ APC ko gbọdọ tuka lẹyin ti oun ba pari saa keji oun tan.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Adesina
Buhari rọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC lati ṣa ipa wọn, ki wọn si rii pe APC lẹgbẹ to siwaju ninu awọn ẹgbẹ oṣelu to wa lẹkun wọn.
Aarẹ Buhari ni iwe itan yoo sọ itan rere nipa awọn ọmọ ẹgbẹ APC lọjọ iwaju, ti onikaluku ba gbiyanju lati ri pe APC fẹsẹ mulẹ lẹkun wọn.












