Nigerians in Oman: Ààrẹ Buhari, ẹ̀yin gómìnà ìpínlẹ̀ Yorùbá, ẹ rántí wa ní Oman, àwọn ọmọ Nàìjíríà
'Ẹ gbà wá o, á ti há sí Oman, ẹ dákun ẹ wá kó wa jáde o'- Awọn ọmọ Naijiria to ha si Oman
Oriṣiiriṣii ọrọ lo ti n jade lati igba ti BBC ti gbe iroyin yii soju opo rẹ pe awọn ọdọbinrin Naijiria n fẹ kuro ni Oman lasiko yii.
Bi awọn kan ṣe ti n gbadura pe ori a ṣọ awọn ọmọ yii de ile pada layọ ni awọn miran n ke si ijọba Naijiria lati tete ran wọn lọwọ.

Bakan naa ni awọn miran n bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu àwọn ọmọbinrin naa pe kini wọn n wa kiri lasiko yii ati pe o yẹ ki tile oge wọn maa to wọn lati jẹ.
Nigba ti awọn miran gba pe ojukokoro lo n fa irinajo ti ko dara lọ silẹ okeere yii.

- Ọlọ́paàá ní wọ́n ṣèèṣì yìnbọn pa ọmọ mi tó ń tọ́ ọmọ oṣù mẹ́rin lọ́wọ́ ni- Ìyá Kager
- Wo Sultan Qaboos bin Said, ẹni tó gbàkóso ìgbé ayé òṣèlú Oman fún àádọta ọdún
- Obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ ẹrú ní orílẹ̀èdè Oman tó bá fẹ́ ní òmìnira, gbọdọ̀ bá ọ̀gá rẹ̀ ṣùn - Obìnrin méjì tó ti Oman dé
- 'Mo fọ kọ́mú, pátá, ògiri ilé lórí N200,000 láìlèfọhùn lórílẹ̀èdè Oman'
- Mò ń tọ̀ s'ára ni mo fi gba ara à mi l'óko ẹrú ní Oman
Ni afikun ijọba ni awọn miran di ẹru naa ru pe ko pese iṣẹ fun awọn ọdọ, bẹẹ ọdọ ni agbara orilẹ-ede.

Awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan ti wọn ha si orilẹ-ede Oman ni wọn ti n rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ Naijiria.
Koda, wọn n kesi awọn ijọba ipinlẹ ẹkun Iwọ oorun guusu Naijiria lati gba wọn silẹ lọwọ wahala ti wọn wa lorilẹ-ede naa ki wọn si ko awọn wale.
- Akanbi mi, má fọ̀ ọ́, mo wà pẹ̀lú ẹ; Ẹni tó ṣe ìgbéyàwó olórùka ló l'ọkọ- Lizzy Anjorin
- Gbogbo orin egúngún bìkiafù tí wọ́n kọ sí mi l'étí nípa Ajayi tí mi o gbọ̀ ló bu mí lọ́wọ́- Akeredolu
- Báwó ni òògùn dexamethasone ṣe ń ṣiṣẹ́ lára
- Ǹjẹ o yẹ kí èèyàn máa sùn lẹ́nu iṣẹ́?
- A ṣe tán láti yọ ìjìyà ikú kúrò nínú àbá ọ̀rọ̀ ìkórìra- Sẹ́nẹ́tọ̀ Sabi
Ki lo ti kọkọ ṣẹlẹ?
Ninu fọran fidio kan ti wọn ṣe ranṣẹ si ileeṣẹ BBC News Yoruba lati fi kan si ijọba ni wọn ti pe fun iranwọ naa.
Awọn eeyan ọhun ni wọn ni iṣẹ aje ni awọn ba de orilẹ- ede Oman ki awọn to ṣeto bi wọn ṣe lọ o to yi idi ọrọ pada.
Wọn ni lẹyin ti awọn de Oman ni awọn fi wa di alarinkiri ni orilẹede naa.
Awọn obinrin naa ṣalaye pe awọn fẹ ki ijọba apapọ o boju wo awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria to wa ni Oman atawọn orilẹ-ede Larubawa miran.
Ati pe ki ijọba dakun gbe igbesẹ lati lee ko wọn pada wa si ile gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe fun awọn to wa lawọn orilẹ-ede miran.