Ramaphosa meets Buhari: Ààrẹ South Africa ṣèpàdé pọ pẹlú ààrẹ Buhari nílùú Abuja

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ Cyril Ramaphosa orilẹ-ede South Africa ti ṣe ipade pọ pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari niluu Abuja lori ọna lati jẹ ki ibaṣepọ to dan mọran wa sii laarin orilẹede mejeeji.
Ọjọru ni Ramaphosa gunlẹ si ilu Abuja fun abẹwo ọlọjọ mẹta sí Naijiria, Ivory Coast, Senegal ati Ghana.
Buhari ati Ramaphosa sọrọ lori bi idokowo papọ orilẹ-ede mejeeji yoo tun ṣe gberu sii.
- Mr & Mrs Kogberegbe: Ṣé lọ́òtọ́ ọkọ àti ìyàwọ́ ní Mr & Mrs Kogberegbe? Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò yìí rèé...
- 'Oṣù mẹ́sàn-án ni wọ́n fi jí mi gbé tí wọ́n ń fipá bá mi lòpọ̀ títí tó fi di oyún'
- 'Gbogbo ọlọ́pàá tó ń gbégidínà lọ́nà àìtọ́, ẹ yọ wọ́n kúrò'
- Mo fún òṣìṣẹ́ tó bá fẹ́ du ipò gómìnà di December 18 láti fi ipò tó wà sílẹ̀ - Gómìnà Fayemi
- Bí àdúrà ọjọ́ kẹjọ àti ayẹyẹ òkú Baba Suwe yóò ṣe lọ rèé
Bakan naa ni wọn tun jijoro lori ọrọ awọn ọdọ ati eto idagbasoke fawọn obinrin.
Fun ọpọlọpọ ọdun ni awọn ọmọ ilẹ South Africa ti maa n ṣe ikọlu si awọn ọmọ Naijiria to jẹ oniṣowo lorilẹ ede South Africa eleyii to ti sakoba fun ajọṣepọ to wa laarin awọn ọmọ Naijiria ati awọn ọmọ ilẹ South Africa.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti ke gbajare pe niiṣe l'awọn ọmọ ilẹ South Africa maa n ji ẹru awọn ko, ti wọn si maa n dana sun un nigba mii.
Bakan naa ni wọn sọ pe awọn ọmọ ilẹ South Africa tun maa ṣeku pa awọn nigba mii tori pe awọn n dokowo nilẹ wọn.
- Kókó méje tó wà nínú ‘White Paper’ ìjọba Eko lórí àbọ̀ ìwádìí ìwọ́de EndSARS
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí méje tó ń pa èèyàn ṣe ètùtù ọlà l‘Ogun
- Agbófinró ti ọ̀pọ̀ òṣìsẹ́ ọba mọ́ ìta ọ́ọ́físì torí àìgba àbẹ́rẹ́ àjẹsára
- Mo ti rí òkú ọmọ mi kan ,mò ń retí ẹlẹ́ẹ́keji-Baba tó pàdánù ọmọ nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi
- Obìnrin ẹni ọdún 28 kú lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ariwo sọ!
- 'Omicron ti wọ Nàìjíríà o', ìjọba àpapọ̀ kéde; Canada bẹ́gi dínà àwọn ọmọ Nàìjíríà tó bá fẹ́ wọlé
- A kò faramọ́ àbájáde ''Endsars Panel Report'', kò sí ẹni tó kú ní Lekki Tollgate sẹ́ẹ̀, "White paper" wa rèé - Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko
Ohun tawon ọmọ orílẹ̀-èdè South Africa n sọ ni pe awọn ọmọ Naijiria n gba isẹ to yẹ ki awọn maa ṣe mọ awọn lọwọ.
Ijọba Naijiria sọrọ tako iwa yii, o si tun pe aṣoju ijọba orile-ede South Africa lori ọrọ naa.
Koda, ijọba Naijiria tun ko awọn ọmọ Naijiria to ha si South Africa wale nigba naa.
Aarẹ Ramaphosa naa tọrọ aforijin lọwọ ijọba Naijiria, ijọba rẹ si ṣeleri pe oun yoo ṣe atunṣe ki alaafia le jọba laarin orilẹede mejeeji tori ipa pataki ti wọn n jọ n ko nilẹ Afirika.

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba Naijiria ati ti South Africa tun buwọ lu iwe adehun lati jẹ ibaṣepọ to dan mọran tun wa sii lẹka ileeṣẹ ologun, iwakusa ati epo rọbi.
Aarẹ Ramaphosa tun lo abẹwo rẹ si Naijiria lati rawọ ẹbẹ s'awọn orilẹ-ede to fofin de irin-ajo sí South Africa tori ẹda covid-19 Omicron to ṣẹyọ nibẹ lati ka ofin naa nilẹ.












