Irọ́ ni pé àwọn kan fẹ́ gbẹ̀mí Yerima nílùú Abuja – Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Yerima ati agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Abuja
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe irọ ni iroyin to n lọ nigboro pe awọn kan fẹ ṣekupa ọmọ ogun to gbena woju minisita fun FCT, Nyesom Wike, iyẹn Lt Ahmed Yerima, niluu Abuja.
Ọlọpaa ni irọ nla gbaa ni gbogbo awọn iroyin to n lọ nigboro pe awọn kan gbiyanju lati ṣekupa ologun naa nitori ko si ohun to jọ bẹẹ.
Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ sọ pe awọn eeyan kan n tẹle ologun naa ninu ọkọ dudu Hilux kan ti ko ni nọmba ti wọn si fi aṣọ bo oju wọn.
Awọn ileeṣe iroyin abẹle kan sọ pe nnkan bii aago mẹfa abọ irọlẹ ni iṣẹlẹ naa waye lagbebe ile epo bẹntiro NIPCO to wa loju ọna marosẹ Kubwa.
Wọn ni awọn eeyan naa gbiyanju lati kọlu Yerima amọ o bọ lọwọ wọn, iroyin yii ni ọlọpaa ti ni ko si ohun to jọ bẹẹ.
Ki ni ọlọpaa sọ ni pato?
Agbẹnusọ ileeeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja, Josephine Adeh sọ loju opo X rẹ pe iṣẹlẹ naa ko waye ati pe ko si ẹnikẹni to fi ọrọ ọhun lọ ni agọ awọn.
Adeh sọ pe "Ileeṣẹ ọlọpaa FCT ti gbọ iroyin to gba igboro kan pe awọn kan fẹ gbẹmi Lt. Ahmed Yerima.
"A fẹ sọ ni okodoro fun yin pe ko si ẹnikẹnikẹni to fi ọrọ naa to wa leti bẹẹ ni ko si iṣẹlẹ kankan to jọ bẹẹ niluu Abuja.
"A fẹ rọ gbogbo araalu ki wọn maṣe naani irufẹ iroyin bẹẹ ki wọn si ṣọra lati maa gbe iroyin ẹlẹjẹ to le da wahala silẹ laarin ilu kiri.

Oríṣun àwòrán, @Jossy_Dannyking
Bi Yerima ṣe di gbajumọ ọsan gangan
Yerima di ilumọọka lasiko ti Wike atawọn ẹmẹwa rẹ fẹ wọ ori ilẹ kan amọ ti awọn ogun di wọn lọna lati wọle.
Ọrọ naa bi Wike ninu o si koju ọmọ ogun to ṣaaju awọn ti ko jẹ ki wọn wọlẹ, amọ gbogbo idunkoko Wike lati jẹ ki Yerima to lewaju awọn ologun naa juwọ silẹ lo ja si pabo.
Bi Wike ṣe n sọrọ to si n jagbe mọ Yerima ni ologun naa n fun lesi pada pẹlu suuru.
Wike n fẹ ki wọn kuro lọna fun oun ki oun le wọ ori ilẹ naa ṣugbọn Yerima atawọn akẹgbẹ rẹ kọ jalẹ.
Ologun ọhun sọ fun Wike pe ọgagun kan to ni irawọ mẹta lo fi oun sibẹ, aṣẹ rẹ si loun n tẹle.
Lẹyinorẹyin, Wike fi agbegbe naa silẹ lẹyin to ju ọwọ silẹ fun ologun ọhun atawọn akẹgbẹ rẹ.
Iṣẹlẹ naa milẹ titi lori ayelujara ti ọpọ awọn alẹnulọrọ ni ẹka eto abo atawọn ajagunfẹyinti ni Naijiria si bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ohun ti Wike ṣe.
Bo tilẹ jẹ pe awọn kan ni ko yẹ ki ologun naa yẹyẹ Wike bo ṣe ṣe amọ fun ọpọ araalu, ẹyin Yerima ni wọn gbe si.















