Olórí ikọ̀ aláàbò tẹ́lẹ̀, Lucky Irabor àti Mínísítà ètò ààbò ìpínlẹ̀, Bello Matawalle, ní Wike ti ṣẹ̀ sí Ààrẹ Naijiria nitori aáwọ̀ òun àti ṣọ́jà

Oríṣun àwòrán, Screenshot/ Facebook
Ko jọ pe ọrọ to ṣẹlẹ laaarin Nyesom Wike ati ṣọja A.M Yerima, nitori ilẹ niluu Abuja ti n bi Ige ati Adubi.
Idi ni pe ọlọkan-o-jọkan eeyan ati ẹka ni wọn n gba iṣẹlẹ ọjọ Iṣẹgun naa bii ẹni gba igba ọti.
Bi awọn kan ṣe n bu Wike ni ọpọ eeyan tun n yin Yerima to gbena woju minisita ilu Abuja naa, wọn ni Yerima ko jẹbi ọrọ, Wike gan-an lo da oju ilana tootọ ru.
Lara awọn to tun ṣẹṣẹ sọrọ nipa iṣẹlẹ naa ni olori ikọ ọmọ ogun alaabo tẹlẹ, Ajagunfẹyinti Lucky Irabor ati Minisita fun eto aabo fun awọn ipinlẹ, Bello Matawalle.
Oju kan naa ni awọn mejeeji yii fi wo ọrọ naa, iyẹn naa si ni pe Nyesom Wike lo tapa si aarẹ Naijiria, nitori ologun to pariwo mọ naa, bii ẹni ri Aarẹ Bola Tinubu fin ni.
Bí ọmọ ogun yẹn kéré jù bẹ́ẹ̀ lọ, aṣojú orilẹede ni-Ajagunfẹyinti Irabor
Nigba to n ṣalaye ero rẹ nipa iṣẹlẹ naa niluu Abuja lanaa, Olori ikọ alaabo tẹlẹ ni Naijiria, Ajagunfẹyinti Lucky Irabor, sọ pe:
"Ẹni to wọ aṣọ ogun kọ la n sọrọ nipa rẹ, bi ko ṣe aṣọ yẹn gan-an to n ṣoju orilẹede Naijiria. Boya ọmọde ologun ni tabi agba ologun, ti o ba sọrọ abuku si wọn tabi o huwa to tako ko wọn, orilẹede lo n tabuku.
"Emi gan-an ti mo jẹ ọga ologun, mi o le gba ṣọja mi leti. Ti mo ba ṣe bẹẹ, mo maa jiya to tọ si mi. Ilana wa ti a maa n tọ lati yanju iru rẹ, ohun to fi ibi ti ofin wa han niyẹn, yatọ si awujọ ti ko si ofin."
Ajagunfẹyinti Irabor fi kun un pe aṣẹ to yẹ ki ṣọja Yerima tẹle lo tẹle, bo ṣe wa ninu iṣẹ ologun niyẹn.
Kò sí ìdí kankan tí wọ́n yóò fi fìyà jẹ ọmọ oloógun yẹn- Matawalle
Loju iwoye tirẹ, Minisita eto aabo ipinlẹ, Bello Matawalle, ṣalaye pe wahala to ṣee dena ni Wike jẹ ko waye pẹlu ọna to gbe ọrọ naa gba.
Ninu ifọrọweọrọ kan to ṣe pẹlu ẹka iroyin DCL Hausa, Matawalle sọ pe o yẹ ki Wike kan si awọn ẹka to yẹ ni, dipo ko maa tahun si ọmọde ṣọja.
O ni oun gbọ pe Minisita ilu Abuja naa ti kan si ọga alaabo tẹlẹ, wọn si ti ni ko ni suuru, awọn yoo ri si ọrọ ilẹ naa.
"Ohun to ṣẹlẹ laaarin Minisita Wike ati ṣọja yẹn buru pupọ, ṣọja yẹn sọ fun un pe aṣẹ ti wọn pa foun loun n tẹle, ko yẹ ki Wike maa ba ologun naa tahun., awọn ọga rẹ lo yẹ ko ba sọrọ"
"Alajọṣiṣẹ kan naa ni awa ati Wike, ko ba ti ba wa sọrọ ka yanju ẹ. Ihuwasi ṣọja yẹn ba ofin mu, nitori bi won ṣe ko wọn niyen.
"Fun idi eyi, ṣọka kekere naa ṣe ohun ti wọn pa a laṣẹ ni, ko si idi kan lati fiya jẹ ẹ, ihuwasi rẹ to ki eeyan gbe oriyin fun un"
" Ṣọja naa ko ṣẹ ẹṣẹ kankan labẹ ofin ologun; tọwọtọwọ lo si sọrọ ti ẹ ba wo o daadaa. Wike ni ko ba ti bọwọ fun aṣọ ologun ti ṣoja wọ"
Matawalle lo ṣe afikun bẹẹ.
Minisita eto aabo fun ipinlẹ naa tẹsiwaju pe ki i ṣe pe oun n ti ologun lẹyin, oun ko si sọ pe wọn ki i bọwọ fun ẹlomiran ninu iṣẹ ologun.
O ni ohun ti oun n ṣalaye ko pe ologun ki i fi aṣẹ wọn ṣere rara.
Ó yẹ ki wọn tọrọ aforiji lọwọọ Wike – PANDEF
Ẹwẹ, ẹgbẹ kan, Pan Niger Delta Forum,( PANDEF), to jẹ ẹgbẹ oṣelu nla ni ẹkun Guusu-Guusu orilẹede yii, ti sọ pe niṣe lo yẹ ki wọn tọrọ aforiji lọwọ Nyesom Wike ni.
Ẹgbẹ naa sọ pe eyi gbọdọ ri bẹẹ nitori wọn di Wike lọwọ lati ṣe iṣẹ rẹ.
Alaga apapọ fun PANDEF, Ambassador Godknows Igali, sọ eyi ninu atẹjade kan to fi sita l'Ojobo.
O ni ki Aarẹ Bola Tinubu paṣẹ pe ki awọn ẹka alaabo ati ofin wadii iṣẹlẹ yii, ki wọn si fi awọn to ba ṣẹ jofin.
Igali sọ pe eyi ni yoo mu ki ẹtọ han ninu iṣẹ ologun, yoo si jẹ ki wọn bọwọ fun awọn to ba wa ninu ijọba.
Alaga naa fi kun un pe iwa ṣọja kekere yii ki i ṣe pe o tabuku Wike lasan, o lo tun fi ai nifẹẹ aarẹ han, bẹẹ agbara aarẹ lo wa lara minisita rẹ to ran niṣẹ.
Emi o fún ṣọja ni móto nitori Wike tí wọ́n jọ ní gbolohun asọ̀ o- Atiku
Bi iroyin Wike ati ṣọja Yerima ṣe gbilẹ kankan ni omiran tun ru jade l'Ọjọruu, pe Atiku Abubakar, igbakeji aarẹ tẹle, fun Ṣọja Yerima ni ọkọ SUV nitori ohun to ṣẹlẹ laaarin rẹ ati Wike.
Eyi ni Atiku sare fesi si, pe ko si ohun to jọ bẹẹ.
Iroyin naa sọ pe ọkọ tuntun Toyota SUV ni Atiku gbe fun ṣọja Yerima.
Ninu ọrọ to fi lede loju opo x rẹ, lanaa, olugbani-nimọran lori iroyin fun Atiku, Paul Ibe, ṣapewjuwe iroyin naa bii irọ gbuu ti ko lẹsẹ nilẹ.
O rọ awọn eeyan lati ma ṣe gba a gbọ rara.
"Ọlọlajulọ Atiku Abubakar, Igbakeji Aarẹ Naijiria lati 1999 de 2007, ko fun Lt. Ahmed Yerima — tabi ẹnikẹni ni ọkọ ayọkẹlẹ tuntun SUV, lodi si iroyin eke to n lọ lori ayelujara.
"Agbelẹrọ pata ni, ki gbogbo eeyan ma ṣe gba a gbọ."
Bẹẹ ni Ibe wi lorukọ Atiku Abubakar.














