Obasanjọ àti Danjuma ti pè mí rí lórí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ l'Abuja, wọn kò fi ológun halẹ̀ mọ́ mi – Wike

Lẹyin ti ọmọ ogun kan, Ahmad Yarima, gbena woju ẹkun minisita fun FCT, Nyesom Wike lori ọrọ ilẹ kan niluu Abuja, minisita naa ti sọrọ lati gbe ara rẹ lẹyin.
Lasiko ti n ba awọn akọroyin sọrọ ṣaaju ipade igbimọ ilu l'Abuja, Wike sọ pe oun ko ni iṣoro kankan pẹlu ileeṣẹ ọmọ ogun bikoṣe pẹlu awọn eeyan kan ti wọn ro pe awọn jẹ alagbara ti ẹnikẹni ko le woju.
Wike bu ẹnu atẹ lu bi ọga ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi tẹlẹ, Zubairu Gambo ṣe ko awọn ọmọ ogun sori ilẹ rẹ ati pe o pọn dandan ki oun lọ sori ilẹ naa nitori oun ko le joko si ọọfisi ki awọn ologun si maa da seria fun awọn oṣiṣẹ oun.
O ni "bawo ni mo ṣe maa joko sinu ọọfisi gẹgẹ bii minisita ti awọn kan a si maa fiya jẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn wa nipo adari?"
Minisita naa ni awọn oṣiṣẹ oun yoo maa bẹru lati ṣiṣẹ wọn ti wọn ba mọ pe oun ko ni le daabo bo wọn.
Ọbasanjọ atawọn mii ti pe mi lori ọrọ ilẹ ilu Abuja ri
Minisita naa ni awọn alẹnulọro lawuji bii Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Olusegun Obasanjo, ati ajagunfẹyinti, Theophilus Danjuma ti pe oun lori aago ri lori ọrọ ilẹ l'Abuja.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, kaka ki awọn eeyan ọhun maa lo agbara wọn, niṣe ni wọn pe oun lori aago lati yanju ọrọ naa.
Wike sọ pe niṣe ni awọn eeyan bii Obasanjo pe oun lori aago dipo ko maa fi ọmọ ogun dunkoko mọ awọn oṣiṣẹ ijọba to wa labẹ oun.
Ọsẹ to kọja ni fidio ariyanjiyan laarin Wike ati ọmọ naa, Ahmad Yarima gba ori ayelujara kan nibi ti Wike ti n sọ fun pe ko gbe ẹnu rẹ dakẹ ti Yarima si n fesi pẹlu igboya pe oun ko ni ṣe bẹẹ.
Fidio ọhun milẹ titi to bẹẹ ti ọpọ araalu fi n bu ẹnu atẹ lu Wike lori iṣẹlẹ naa ti inu pupọ ninu wọn si n dun pe minisita ọhun ti pade ọkọ rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọmọ ogun ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa, wọn fi ọrọ kan bii owe soju opo X wọn to n jọ bii pe wọn wa lẹyin ohun ti ọmọ ogun naa ṣe digbi.
Ẹwẹ, ọpọ araalu lo bu ẹnu atẹ lu Wike ti wọn si wa lẹyin ologun naa.
Wo ìlànà mẹ́rin tí òfin là kalẹ̀ tí ọmọ ogun le gba àṣẹ àti àwọn tó lè gba àṣẹ lọ́wọ́ wọn

Oríṣun àwòrán, AFP
Láti ìgbà tí ìfaǹfà ti wáyé láàárín mínísítà fọ́rọ̀ ìlú Abuja, Nyeson Wike ti wáyé àti ológun kan ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni onírúurú ìbéèrè ti gba ẹnu àwọn èèyàn lórí bí ìlànà gbígba àṣẹ ṣe máa ń wáyé nínú iṣẹ́ ológun.
Ẹ ó rántí pé ní ọ̀sán ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni fídíò kan gba orí ayélujára èyí tó fa awuyewuye láàárín àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Nínú fídíò náà ni mínísítà fun olú ìlú orílẹ̀ èdè yìí, Nyesom Wike àti ọmọ ogun ojú omi kan ti ń tahùn síra wọn.
Ohun tó jọ ni pé ọ̀rọ̀ ilẹ̀ kan ló ṣokùnfà àìgbọ́ra ẹni yé tó wáyé láàárín mínísítà àti ọmọ ogun náà.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló wáyé nígbà tí Wike àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba fẹ́ wọ orí ilẹ̀ kan ṣùgbọ́n tí ọmọ ogun náà dáwọn dúró wí pé wọn kò lè wọ ibẹ̀.
Báwo lòfin ṣe là á kalẹ̀ fún ọmọ ogun láti gba àṣẹ?
BBC kàn sí ajagunfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ológun orí omi, Ọ̀gágun Umar Bakori ẹni tó ṣàlàyé pé bákan náà ni ọ̀rọ̀ iléeṣẹ́ ológun ṣse rí káàkiri àgbáyé, tó sì jẹ́ pé ó ní bí wọ́n ṣe ń gba àṣẹ láti òkè délẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé ìbọ̀wọ̀ fún ẹni tó bá júni lọ nípò jẹ́ ohun tí wọn kìí fi ṣeré rárá nínú iṣẹ́ ológun kódà kó jẹ́ pé wọ́n jọ wọ iṣẹ́ lásìkò kan náà.
Ó ní àwọn èèyàn kan wà tó jẹ́ pé ó pọn dandan fún ológun láti tẹ̀lé àṣẹ wọn láì ní gbé ohun tí wọ́n bá sọ yẹ̀wò.
Àwọn tó kà náà ni:
- Ààrẹ orílẹ̀ èdè
Ọ̀gágun Bakori ní gẹ́gẹ́ bí òfin Nàìjíríà àti òfin àwọn ológun ṣe là á kalẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé alágbádá ni ààrẹ, òun ni olórí àkọ́kọ́ fún ilé ológun.
Ó ní èyí jẹ́ kó pọn dandan pé àṣẹ tí ààrẹ bá pa gbọdọ̀ jẹ́ ohun tí àwọn ológun gbọdọ̀ tẹ̀lé níbikíbi.
- Ọ̀gá tó bá wà nípò tó ṣaájú
Lẹ́yìn ààrẹ, Bakori ṣàlàyé pé ẹni tó tún le pàṣẹ fún ológun láti ṣe ohunkóhun tí yóò sì tẹ̀le ni ẹni tó bá tún jù ú lọ nípò nínú iṣẹ́ ológun.
Ó fi kun pé tí ọ̀gá ológun kan bá pàṣẹ kan fún ẹni tọ kéré si ẹni náà gbọdọ̀ tẹ̀lé àṣẹ náà kódà bó jẹ́ ohun tí kò tọ́ ni.
"Tí ẹni tó bá ju ẹni tó kọ́kọ́ pàṣẹ yẹn bá ri pé àṣìṣe wà, kò ní wọ́gilé àṣẹ tí ẹni àkọ́kọ́ pa dípò bẹ́ẹ̀ ó máa gbà á nímọ̀ràn láti sọ fun pé kó yí àṣẹ náà padà.
- Mínísítà fọ́rọ̀ ààbò
Bakori sọ pé àwọn ìgbà míì wà tí mínísítà fétò ààbò máa pàṣẹ tí àwọn ológun yóò sì tẹ̀lé àṣẹ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ó ní ó wà nínú òfin pé ààrẹ ni olórí ìgbìmọ̀ ààbò orílẹ̀ èdè ṣùgbọ́n aṣojú rẹ̀ ni mínísítà fọ́rọ̀ ààbò jẹ́, ó ní fún ìdí èyí ó le pàṣẹ fáwọn ológun, tí wọ́n yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀.
- Adelé ààrẹ
Ọ̀gágun náà tún fi kun pé òfin iléeṣẹ́ ológun fààyè gba ẹni tó bá ń delé gẹ́gẹ́ bí ààrẹ láti pàṣẹ fáwọn ológun.
Bakori ní lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, kò sí ẹni tó lè pàṣẹ fún ológun, tí wọ́n sì máa mú àṣẹ náà ṣẹ.
Kí ló dé tí ológun Yerima kò ṣe tẹ̀lé àṣẹ Wike?
Ọ̀gágun Bakori ṣàlàyé pé Yerima kọ̀ láti tẹ̀lé àṣẹ mínísítà ìlú Abuja, Nyesom Wike nítorí kò sí nínú àwón tí òfin iléeṣẹ́ ológun gbà á láàyè láti tẹ̀lé àṣẹ wọn.
"Òfin tó de ẹni tí ológun gbọdọ̀ tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ kò ka mínísítà fọ́rọ̀ ìlú Abuja mọ, nítorí náà ni àwọn ológun tó wà níbẹ̀ kò ṣe tẹ̀le."
Ó ṣàlàyé pé nírú ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀, kò sí bí àwọn ológun náà ṣe máa tẹ̀lé àṣẹ kankan lòdì sí àṣẹ tí wan ti kọ́kọ́ fún wón àti pé ọmọ ogun tó bá kọ̀ láti tẹ̀lé àṣẹ ẹni tó bá jù ú lọ nípò máa kojú ìjìyà tó lágbára.
Ó fi kun pé lábẹ́ òfin iṣẹ́ ológun, ọ̀gá kò gbọdọ̀ fún ọmọṣẹ́ abẹ́ rẹ̀ ní iṣẹ́ tí kò lè jẹ́ nítorí ẹni tí kò bá tẹ̀lé àṣẹ ọ̀gá rẹ̀ máa kojú ìgbẹ́jọ́ pé ó fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀.















