Àwọn asòfin Ondo bínú jáde níbi ìjókòó ilé torí abá àfikún ètò ìsúná ₦531bn tí Gomina Aiyedatiwa gbé lọ iwájú wọn

Wahala nla sẹlẹ ni Ile igbimọ asofin Ipinlẹ Ondo bi awọn asofin ṣe fariga lati joko fun ijiroro lori aba afinku eto isuna ọdun 2025 ti iye rẹ jẹ ₦531 billion.
Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa lo gbe àfikún aba ìṣúná náà siwaju wọn lati bu ọwọ lu.
Awọn asofin naa sọ pe awọn ko ni joko lati bọwọ lu afinku eto isuna naa nitori ida marundinlogun isẹ ni ijọba ṣe ninu eto isuna ọdun yii ti wọn ti bọwọ lu saaju.
Ijọba Aiyedatiwa ko kogo ja lati pe fun afinku eto isuna miran
Àwọn aṣòfin náà ṣàlàyé pé eyi safihan rẹ pe ijọba Aiyedatiwa ko kogo ja lati pe fun afinku eto isuna miran, paapaa julọ bi ọdun yi ṣe din díẹ̀ ni oṣu meji ko bùṣe.
BBC News Yorùbá gbọ pe marundinlogun ninu ọmọ ile igbimọ asofin naa lo kọ jalẹ lati buwọ́lù afinku eto isuna yii, ti wọn si koju olórí ile, aṣòfin Olamide Oladiji.
Awọn asofin naa kọ jalẹ lati joko fun ijiroro bi wọn ṣe sọ pe olórí n gbiyanju lati jẹ ki wọn buwọlu afinku eto isuna eyi ti Gomina Lucky Aiyedatiwa gbe wa siwaju ile.
Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe waye?
Ni ọjọ iṣẹgun ọsẹ yi ni Akọwe ile igbimọ asofin Ipinlẹ Ondo, Amofin Benjamin Jayeola ka aba afinku eto isuna, eyi ti Gomina Lucky Aiyedatiwa gbe lọ iwaju igbimọ asofin naa.
Ni kete to kaa tan, ní olórí ile naa, sọ fun igbimọ to n bojuto eto isuna eyi ti aṣòfin Oluwọle Ogunmolasuyi n dari, lati se ọfintoto aba naa.
Lẹyin eyi ni awọn ọmọ ile igbimọ asofin naa fariga, tí wọn si jade lọkọọkan lẹyin ariyanjiyan to lagbara lori aba afinku eto isuna naa.
Ohun tí a ń béèrè ní pe ki ni ìjọba fi owó tí a buwọ́lù ṣáájú ṣe?
Ọkan lara awọn ọmọ ile aṣòfin Ondo to ba BBC News Yorùbá sọrọ, Ifabiyi Olatunji salaye pe wọn ko pari ijoko ọjọ naa, ti àwọn fi tuka.
O ni ariyanjiyan bẹ silẹ nitori àwọn n beere pe ki ni ijọba fi owo ti wọn buwọ lu saaju ṣe?
Ọgbẹni Fabiyi sọ pe lóòótọ́ ni ijọba lẹtọ lati gbe aba eto isuna wa siwaju ile, ẹtọ àwọn asofin naa si ni lati beere awọn ibeere to tọ lori eto isuna naa.
O salaye pe wọn gbudọ ri daju pe aba eto isuna naa gbajumọ eto igbaye gbadun awọn eeyan ti wọn soju fun.
Asofin naa fẹsun kan olórí ile igbimọ asofin naa pe o lẹdi àpò pọ pẹlu Gomina lati le fohun tẹ lu aba naa.
Fabiyi salaye pe ijọba Aiyedatiwa kuna lati se imuṣẹ awọn isẹ akanse ti eto isuna ọdun 2025 gbajumọ, idi rẹ niyi ti ko fi lẹtọ lati pe fun afikun eto isuna ọdun yi.
Gẹgẹ bi O se wi " ẹ wo ipo ti Ipinlẹ Ondo wa, ko si ohun to n sẹlẹ nipinlẹ yi, gbogbo opopona ti ijọba Gomina Odunayo Akeredolu ń ṣe lọ ki o to jẹ ipe Ẹlẹda ni Gomina Aiyedatiwa ti pati "
Kí ni ìjọba Ìpínlẹ̀ Ondo sọ lórí ọ̀rọ̀ náà?
Kọmisọna feto iroyin n'ipinlẹ Ondo, Idowu Ajanaku sọ pe, lootọ ni wọn gbe aba afinku eto isuna fun ọdun 2025 lọ ile igbimọ asofin.
Ọgbẹni Ajanaku sọ pe irọ to jina si ootọ ni pe iyapa wa laarin awọn asofin naa lori bí buwọ́lù lu eto isuna naa.
O sọ pe gbogbo awọn aṣòfin merindinlọgbọn nile naa ni yoo bọwọ lu afinku eto isuna naa lai si ikun sinu tabi wahala kan.















