Ohun tó fa ikú èèyàn mẹ́fà àti ọ̀pọ̀ tó farapa lásìkò tí wọ́n fẹ́ gba iṣẹ́ ológun ní Ghana rèé

Oríṣun àwòrán, @Ghana Presidency
Ọna ọfun, ọna ọrun!
Ko din ni eeyan mẹfa to padanu ẹmi wọn l'Ọjọru ana, ọjọ kejila, oṣu Kọkanla ọdun 2025, lasiko ti wọn n ṣeto igbani-siṣẹ ologun lorilẹede Ghana.
Yatọ si awọn to di oloogbe, ọpọ eeyan la tun gbọ pe wọn farapa nibi eto naa.
Awọn fidio lori ayelujara lanaa ode yii, ṣafihan bi awọn eeyan to fẹ gba iṣẹ ologun naa ṣe to lọ loju opopona.
Aago meji oru ni awọn mi-in si ti ji de ibi eto igbani-siṣẹ ọhun.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ologun ilẹ Ghana ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, wọn ni awọn to farapa n gba itọju lọwọ ni ileewosan awọn ologun ti i ṣe 37 Military Hospital.

Kí ló fa akọlù-kọgbà tó mú ẹ̀mí lọ?
Gẹgẹ bi atẹjade awọn ologun ilẹ Ghana ṣe wi, ohun to fa iku ojiji ati ifarapa naa ni pe:
" Iwadii ti a kọkọ ṣe fi han pe awọn eeyan to fẹ gba iṣẹ ologun pọ ju ni papa iṣere El-Wak, nibi ti wọn ti tapa si ofin aabo, ti wọn rọ wọle ki eto naa too bẹrẹ rara ni aago mẹfa owurọ.
"Awọn olutọju n ṣiṣẹ iwosan lati mu ki ara awọn to farapa balẹ, a si ti ṣeto bi a ṣe maa fi to ẹbi awọn to ṣe alaisi leti."
Ọjọ Kejila si ikẹta oṣu Kọkanla yii ni wọn ya sọtọ fun eto igbani-siṣẹ ologun naa ni awọn ibudo ọtọọtọ ni Ghana.
Ààrẹ Mahama ṣàbèwò sí àwọn tọ́rọ̀ kàn nílé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, @Ghana Presidency
Aarẹ ilẹ Ghana, John Mahama pẹlu awọn lọga-lọga ti ṣabẹwo si awọn eeyan to farapa ninu ijamba naa, iyẹn nile iwosan awọn ologun 37 Military Hospital.
Aarẹ Mahama paṣẹ pe ki awọn ologun fopin si igbanisiṣẹ naa lasiko yii na, titi di igba ti aṣẹ lati tẹsiwaju yoo to wọn lọwọ.
Bi eyi ṣe n lọ lọwọ ni awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ati awọn ẹgbẹ awujọ kan ti n pe fun iwadii iṣẹlẹ naa.
Adari 37 Military Hospital, Ọgagun Evelyn Vivian Abraham-Kwabiah, sọ fawọn oniroyin pe:
"Eeyan mejidinlọgbọn (28) ni ijamba yii kan, awọn mẹfa ku, awọn marun-un wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan orun, awọn mejila mi-in si wa nipo ti ko fi bẹẹ le ju, awọn yoku ti wa nipo alaafia, ko si si ewu kankan lorii wọn."
Aarẹ Mahama sọ pe obinrin ni awọn eeyan mẹfa to di oloogbe naa.

Oríṣun àwòrán, @Ghana Presidency












