Ẹbí Aloba kìlọ̀ fún ìyàwó Mohbad láti máṣe jẹ́ orúkọ àwọn mọ́, Wunmi bá fárígá

Mohbad wọ aṣọ dúdú, dé fìlà tó ṣí ẹnù rẹ̀ sókè

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT/INSTAGRAM

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Àwọn ẹbí olórin tàkasúfèé, Ilerioluwa Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad tó dólóògbé lọ́dún 2023 ti sọ fún ìyàwó olóògbé náà láti yé jẹ́ orúkọ ẹbí àwọn mọ́ títí tí èsì àyẹ̀wò ìwádìí láti fi mọ́ bóyá Mohbad ló ni ọmọ ọwọ́ rẹ̀, Liam ìyẹn DNA fi máa jáde.

Bákan náà ni wan tún pè fún ìwádìí òótọ́ lórí ohun tó ṣokùnfà ikú Mohbad.

Àtẹ̀jáde kan tí olórí ẹbí náà, Omolayo Aloba àti Bàbá Mohbad, Joseoh Aloba fi léde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun sọ pé àwọn ṣì dúró digbí láti wádìí ikú ọmọ náà àti pé àwọn ti gba agbẹjọ́rò míì tó máa má báwọn dá sí àwọn nǹkan ìní tó níṣe pẹ̀lú Mohbad àti ọ̀rọ̀ DNA.

Wọ́n ní àwọn ṣì dúró lórí ẹsẹ̀ àwọn pé àwọn ń fẹ́ ìwádìí tó gbòòrò láti fìdí ohun tó ṣokùnfà ikú Mohbad múlẹ̀, kí òótọ́ fojú hàn, kí àwọn s]I rí idájọ́ òdodo gbà lórí ikú Mohbad.

"Ẹbí Aloba ti fẹnukò láti yan agbẹjọ́rò Oladayo Ogungbe ní ilé iṣẹ́ òfin Ogungbe & Ogungbe gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò kan ṣoṣo tó máa ma ṣojú ẹbí lórí àwọn ẹjọ́ tó bá níṣe pẹ̀lú DNA àti àwọn ilé tó nííṣe pẹ̀lú Ileriolawu Aloba (tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad).

"Síwájú si, ẹbí tún fẹnukò lápapọ̀ pé agbẹjọ́rò Whab Shittu máa tẹ̀síwájú láti máa ṣojú ẹbí lórí àwọn ẹjọ́ tó nííṣe pẹ̀lú ìwádìí lórí ohun tó ṣokùnfà ikú Mohbad."

Lórí ọ̀rọ̀ ilé ìgbé tí Mohbad fi sáyé, ẹbí fi orúkọ èèyàn mẹ́ta léde tí yóò máa ṣè àkóso àwọn ohun ìní tí olóògbé náà fi sáyé.

Àwọn èèyàn náà ni Ajewole Aloba, Rasaq Famuyiwa àti Alonge Aloba.

'A máa fún Wunmi láṣẹ láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé Mohbad tí àyẹ̀wò DNA bá sọ pé Liam ló ni ọmọ'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọ́n ní àwọn alákòso náà ni wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti bèèrè fún àwọn ohun ìní rẹ̀, tó fi mọ́ ilé, ilẹ̀, àwọn owó tó ń wọlé fún-un nídìí iṣẹ́ orin, àwọn nǹkan tó ní láwọn ilé ìfowópamọ́.

Àtẹ̀jáde náà tẹ̀síwájú pé wọ́n fi ààyè kan sílẹ̀ fún ìyàwó olóògbé, Wunmi Adebanjo láti darapọ̀ mọ́ àwọn alákòso náà àmọ́ tí èyí máa wáyé tí ìwádìí DNA bá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ojúlówó ọmọ Mohbad ni Liam jẹ́.

Wọ́n fi kun pé kí Wunmi dènà láti máa pe ara rẹ̀ ní Aloba mọ́, kó sì yé lo orúkọ náà nínú àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀ títí tí èsì àyẹ̀wò DNA fi máa jáde àti tí ébí bá fún-un ní àṣẹ láti máa lo orúkọ náà.

Wọ́n ní ìgbéyàwó àṣà Yorùbá láà'rín Wunmi àti Mohbad kó tó jáde láyé gẹ́gẹ́ bí àṣà Yorùbá ṣe là á kalẹ̀ nítorí wón kò san owó orí rẹ̀.

Wọ́n ní tí ìwádìí DNA bá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Mohbad ló bí Liam ní tòótọ́, àti ìyá àti ọmọ ni wọ́n máa fi ààyè gbà lórí ìṣàkóso àwọn ohun ìní Mohbad.

Bákan náà ni wọ́n ró àwọn èèyàn láti ṣe sùúrù, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ìgbẹ́jọ́ tó ń lọ lọ́wọ́ lórí ikú Mohbad àti pé àwọn kàn fẹ́ fi àyẹ̀wò DNA fìdí àwọn nǹkan múlẹ̀ ni, pé kìí ṣe láti tàbùkù ẹnikẹ́ni.

Ẹbí náà sọ pé ìgbésẹ̀ ṣíṣe àyẹ̀wò DNA náà ń wáyé láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀ lábẹ́ òfin àti pínpín àwọn ogún Mohbad lọ́nà tó yẹ.

Wọ́n fi kun pé àwọn máa kéde ọjọ́ láti fi ṣètò ìsìnkú Mohbad ní kété tí ìgbẹ́jọ́ tó ń lọ lọ́wọ́ bá ti wá sópin, tí wọ́n sì yanjú ọ̀rọ̀ ẹbí tán.

Kò sí ẹni tó le ní kí n má jẹ̀ ẹ́ Aloba mọ́

Iléeṣẹ́ ìròyìn The Punch nínú ìròyìn tí wọ́n gbé jáde lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kọkànlá sọ pé agbẹjọ́rò Wunmi, Kabir Akingbolu bu ẹnu àtẹ́ lu ìdarí ẹbí Aloba fún bí wọ́n ṣe ní kí oníbàárà òun má jẹ̀ẹ́ orúkọ ọkọ rẹ̀ mọ́.

Akingbolu tó ń ṣojú Wunmi lórí ọ̀rọ̀ DNA àti àwọn ohun ìní Mohbad sọ pé àtẹ̀jáde náà jẹ́ ojúnà láti ṣi àwọn aráàlú lọ́kàn lórí àyẹ̀wò DNA náà.

Ó ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwón ẹbí ti gba àṣẹ láti ilé ẹja láti ṣe àyẹ̀wò DNA fún Liam ṣùgbọ́n tí wón kò ní yọjú mọ́ lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ bá ti fún wọn láṣẹ tán.

"Àwọn ni wan máa gba ilé ẹjọ́ lọ láti bèèrè fún àṣẹ láti ṣe àyẹ̀wò DNA, ṣùgbọ́n wọ́n máa sá lọ tí àsìkò àyẹ̀wò náà bá tit ó.

"Ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la kọ lẹ́tà ránṣẹ́ sí wọn lórí àyẹ̀wò DNA yìí tí wọn kò fèsì.

"Lẹ́yìn náà ni wọ́n tún padà wá sílé ẹjọ́ pé òke òkun ni àwọn ti fẹ́ kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò náà tí ilé ẹjọ́ sì tún fún wọn láṣẹ àmọ́ wọn kò yọjú.

"Ìgbà kẹta rèé tí wọ́n máa gbé ẹjọ́ dìde lórí ọ̀rọ̀ DNA, tí wọ́n sì sọ pé ilé ìwòsàn kan ní òkè òkun ni àwọn ti fẹ́ kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò náà àmọ́ a ò ní gba èyí nítorí àwọn kọ́ ni wọ́n máa la ilé ìwòsàn tí àyẹ̀wò náà ti ma wáyé lé ilé ẹjọ́ lọ́wọ́.

Akingbolu fi kun pé Wunmi ti ṣetán láti ṣàyẹ̀wò DNA fún ọmọ rẹ̀, tí kò sì lẹ́bọ lẹ́rù kankan nítorí ọmọ rẹ̀ kìí ṣe ọmọ alè.

Nígbà tó ń ọ̀rọ̀ lórí bí ẹbí Aloba ṣe ní kí Wunmi yé lo orúkọ àwọn mọ́, Akingbolu ní ọ̀rọ̀ náà kò bá òfin mu nítorí tọkọtaya ni Wunmi àti Mohbad kó tó jáde láyé.