Ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run ń gbà bá èèyàn sọ̀rọ̀, kò yẹ kí ẹ̀sìn máa fa ìjà - Bíṣọ́ọ̀bù Ladigbolu
Bíṣọ́ọ̀bù àgbà, Ayo Ladigbolu ti sọ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kò yẹ kó máa dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn.
Bíṣọ́ọ̀bù Ladigbolu tó jẹ́ àgbà ẹlẹ́sìn Kristẹni tó fẹ̀yìntì gẹ́gẹ́ bí Bíṣọ́ọ̀bù nínú ìjọ Methodist Church nínú ìfọ̀rọ̀wérò tó ṣe pẹ̀lú BBC News Yorùbá sọ pé òun kò rò pé ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn máa dá ìjà sílẹ̀ rárá.
Ó ní ọkàn ẹni ló máa ń ṣe ìdarí ẹ̀sìn tí èèyàn yóò ṣe láyé nítorí ọkàn ẹni ni ìgbàgbọ́ ẹni wà.
Ó sọ pé inú ẹ̀sìn Islam ni wọ́n bí òun sí ṣùgbọ́n òun gbàgbọ́ pé ìrìnàjò ayé òun ló gbé òun wọ inú ẹ̀sìn ìgbàgbọ́.

"Ní gbogbo ẹbí wa, ẹ̀sìn mùsùlùmí ni a gbà, nípa bẹ́ẹ̀ tí ẹ bá ríbi tí wọ́n ti ń jìjà ẹ̀sìn, ẹ ò lè rí irú àwa níbẹ̀."
Ladigbolu ní òun gbàgbọ́ pé nǹkan tí ọkàn ẹni bá gbàgbọ́ pé òun ló tọ̀nà jù ló máa sọ bí ẹ̀sìn tí èèyàn náà máa ṣe.
Ó wòye pé kò yẹ kí ẹlẹ́sìn kan máa sọ fún ẹlòmíràn pé ẹ̀sìn rẹ̀ kò da nítorí kò mọ ọkàn àti inú ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀ àti bí ó ṣe súnmọ́ Ọlọ́run tó.
"Nígbà tí mo gba ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ láàárín gbùngbùn ẹ̀sìn Mùsùlùmí, tí kìí bá ṣe pé Ọlọ́run fún àwọn ara Oyo ní sùúrù, wọn ò bá pamí.
"Mo gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kó sí àwọn tí wọ́n bími nínú nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé kò yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn fa ìjà."
Bíṣọ́ọ̀bù náà ṣàlàyé pé kìí ṣe pé èèyàn kan ló wàásù fún òun láti gba ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ tí òun sì gbàgbọ́ pé bí Ọlọ́run ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ yàtọ̀ sí ara wọn.
















