Àwọn akẹkọọ fásitì Ilesa fọnmú mọ́ ìjọba Osun lọ́wọ́ torí àfikún owó ilé ẹ̀kọ́ àti owó ilé tó ju agbára wọn lọ

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fásítì Ilesa ni Ipinle Osun tí ń gbéná woju ìjọba ìpínlẹ̀ náà lórí àfikún owó ẹ̀kọ́ wọn.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, tí wọn ṣe ìfẹ̀hónúhàn ṣàlàyé pé Ile igbimọ asofin ati gomina Adeleke lo kọ eti ikun sii iya n to n jẹ àwọn nile ẹkọ wa.
Wọn fikùn pé kii ṣe wi pe àwọn sadede jade fun ifẹhonuhan àmọ́ nígbà ti ijọba ipinlẹ Osun ati awọn alasẹ ilé ẹ̀kọ́ Fasiti Ilesa ko ri táwọn ro, ni àwọn ṣe kigbe sita.

Ṣáájú iwọde ni a ti kọwe si Ile igbimọ asofin, ọga ọlọpaa, Ọwa Obokun ati awọn èèkànlú miran, ṣùgbọ́n ti ko mu eso kankan jade"
Ọkan lara awọn akọkọ to ṣe iwọde ni ile ẹkọ fasiti to wa ni iluu Ilesa, Ọlalekan Johnson ba BBC News Yoruba sọrọ nípa ìdí tí wọ́n ṣe gùnlé ìwọ́de náà.
Olalekan sọ pé ìgbà mẹta ni awọn ti se ifẹhonuhan, ti àwọn si ti gbe ifẹhonuhan naa de ile igbimọ asofin ni ipinlẹ Ọsun.
Gẹ́gẹ́ bo se wi, eredi ìwọ́de náà da lori bi iya n ṣe jẹ àwọn pẹlu bii owo ile ti àwọn akẹkọ ń gbé ni ilu Ilesa ati eyii ti àwọn ń gbé ninu ọgba Fasiti, ṣe ju agbara àwọn lọ.
"Sugbọn, saaju iwọde ni a ti kọwe si Ile igbimọ asofin, ọga ọlọpaa, Ọwa Obokun ati awọn èèkànlú miran, ṣùgbọ́n ti ko mu eso kankan jade."
Ọlalekan tun tẹsiwaju pe, lẹhin ti ìfẹ̀hónúhàn waye lọjọ Aje ọjọ Kẹẹwa osu Kọọkanla, ní àwọn se ipade pọ pẹlu awọn igbimọ Ile ni ọjọ Ìṣẹ́gun.
"Bo ti le jẹ pe irọ to jìnà si ootọ ni gbogbo ohun ti wọn sọ, nitori ọna ti olukaluku yoo fi jare ni wọn ń wá.
Olalekan ni owo ile ẹkọ awọn akẹkọọ to wa ni ẹka to ri si imọ pipo ogun oyinbo pọ àti imọ isegun ti gbẹnu soke ju agbara lọ bayii.
O ni ara awọn oun ti awọn ṣe iwọde le lori nìyẹn.

"Fásitì Ilesa tí mu adinku ba owo ilegbe to jẹ ti fasiti lati ẹgbẹrun lọna igba Naira (200,000) pada si ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (150,000)"
BBC News Yoruba kan si agbẹnusọ Fasiti Ilesa, Babatunde Fanawọpọ.
Babatunde ni ootọ ni wi pe awọn akẹkọ ṣe iwọde ifẹhonuhan lori bi owo ilegbe wọn ṣe gbẹnu soke ju agbara awọn obi wọn lọ.
Babatunde ni kete ti awọn onile ati abaniwale gbọ pe Fasiti ti de ilu Ilesa ni wọn ti gbowo le owo ile nilu Ilesa ati awon ilu to sunmọ Fasiti naa.
"Bí gbogbo nnkan se n lọ bayii, ó seese ko mú ifasẹyin ba Ile ẹkọ Fasiti Ilesa latari bi gbogbo owo ile ṣe le koko mọ awọn akẹkọ.
Nitori nigba ti agbara ko ba ka owo Ile mọ, awọn akẹkọ yoo bẹ̀rẹ̀ si ni mọ gba fọọmu Ile ẹkọ miran.
Eleyi le jẹ ki ifasẹhin ko de ba Fasiti iluu Ilesa."
Babatunde ni awọn igbimọ ile ẹkọ fasiti ti fori kori lori ọrọ naa.
"Eleyi lo mu ki awọn igbimọ naa mu adinku ba owo ilegbe to jẹ ti fasiti lati ẹgbẹrun lọna igba Naira (200,000) pada si ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (150,000).
Eyi ni awọn igbimọ fasiti fori ko si lati jẹ iranlọwọ fun awọn akẹkọ to ba ni anfaani."
Babatunde tẹsiwaju pe Ootọ ni pe wọn fi kun owo ile ẹkọ awọn ẹka kan ni fasiti Ilesa sugbọn ki ṣe gbogbo awọn akẹkọ ni ọrọ naa kan.

APC Osun sọ oko ọrọ si ìjọba lórí ìnira to ni ó ń mú báwọn akẹkọọ
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC nipinlẹ Osun kò dakẹ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, sọ sì ń ju oko ọrọ si ìjọba Osun lórí àfikún to bá owo ilé ẹ̀kọ́ àti ilegbe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fásítì Osun.
Nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC nipinlẹ Osun, Olabisi Kolawole, ni bi awọn ko ba ri tabi ti awọn ko ba mọ, awọn ko ni sọ sita.
O ni owo ti gomina Ademola Adeleke ti gba ti to Trillion kan Naira, ti ko si han lara ẹto ẹkọ rara.
Olabisi, ni kaaka ki gomina Adeleke mu adinku ba owo awọn akẹkọ ile ẹkọ giga, ṣe ni o tun fi n kun owo naa ni gbogbo igba.
O ni ìjọba Osun ko tun pese ile igbe fun awọn akẹkọ naa, ti gómìnà Adeleke sì ń nawo si àwọn ohun ti ko tọ kiri.
Olabisi, ni eto ẹkọ nikan kọ lo mẹhẹ nipinlẹ Osun lọwọlọwọ bayii torí Gomina Adeleke tun kuna ninu eto ọgbin fun awọn agbẹ ati bẹẹbẹ lọ.
"Ẹgbẹ oselu APC ko sọ ohun ti a ko ri, ohun ti a rí, ni a fi to ara iluu leti, ẹ jẹ ki gomina Adeleke ṣe akanti bo ṣe na owo naa."

Agbẹnusọ gomina Adeleke fèsì lori ìwọ́de àwọn akẹ́kọ̀ọ́
Olawale Rasheed, tíí ṣe agbẹnusọ fún gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tí wá fèsì lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Olawale ni ẹsun ti awọn ẹgbẹ oselu APC fi kan isejọba gomina Adeleke jẹ irọ to jina si ootọ ọrọ gidigidi ni, ibani lorukọ jẹ ni.
Rasheed, ni oun ti awọn akẹkọ ile ẹkọ fasiti iluu Ilesa ṣe iwọde fun, ni ko kan gomina Adeleke rara nitori ọrọ naa ti wa ni iwaju awọn ile igbimọ asofin ti ipinlẹ Ọsun tẹlẹ.
O tun fi kun wi pe, awọn ẹgbẹ oselu APC ti mọ wi pe awọn araalu ko gba ti awọn mọ rara ati pe awọn ko le rọwọ mu ninu idibo si ipo gomina ni ọdun 2026.












