Prophet Mohammed: Àwọn olórí lágbáyé tó ti wọ inu sàréè Ànọ́bi Muhammad tó wà ní Medina rí

Oríṣun àwòrán, @alriyadhdaily
Ọpọlọpọ awọn olori orileede lo ti wọ inu ibi saree Anọbi Muhammad (SAW), eleyi to jẹ ọkan lara ibi to ṣe pataki julọ ninu Islam.
Ni osu karun ọdun 2021, awọn alaṣẹ orilẹede Saudi ṣi yara ibi ti wọn sin Anọbi Muhammad si fun Olotu ijọba Pakistan, Imran Khani lati wọ ni mọṣalaṣi Anọbi to wa ni Medina.
Imran sabẹwo si mọṣalaṣi naa, wọn si gba a laye lati wọ inu ile Nana Aisha ati iboji Anọbi (SAW).
Ninu ile naa ni iboji anọbi, iboji awọn alabarin rẹ gbogbo titi kan awọn Kalifa meji akọkọ ninu ẹsin Islam, Abu Bakr RA ati Umar RA.
BBC ri ẹkunrẹrẹ iroyin gba latọdọ awọn alaṣẹ to wa ni isakoṣo awọn mọṣalaṣi meji to ga julọ ni Saudi Arabia Haramain Sharifain, wọn ṣalaye awọn olori orileede to ti lanfani ati wọ ibi iboji Anọbi Muhammad.
Haramain Sharifain ṣalaye pe ọpọ awọn olori ijọba ni Saudi Arabia ati kaakiri agbaye ni wọn ti fun lanfani lati wọ ibi saree.
Awọn aṣiwaju ijọ orileẹde Pakistan.

Oríṣun àwòrán, @MaryamNSharif
Aṣiwaju ẹsin yii ni olotu ijọba Pakistan tẹlẹ ri, bẹẹ si ni Imran Khan kọ ni olori orileede Pakistan akọkọ ti yoo ri anfani lati wọ ibẹ.
Olootu ilẹ Pakistan tẹlẹ, Muhammad Nawaz Sharif to jẹ olootu to pẹ ju lori oye naa wa lara awọn adari ti awọn alaṣẹ Moṣalaṣi nla mejeeji to wa ni Saudi Arabia sọ pe wọn ṣilẹkun saare Anọbi fun.
Nawaz ti fi fọto ara rẹ si oju opo Twitter ri to ṣafihan asiko to ṣẹbẹwo si Moṣalaṣi Anọbi ni Medina lọdun 2015 ati ọdun 2018.
Aarẹ orilẹede Chechnya, Ramzan Kadyrov

Oríṣun àwòrán, @alriyadhdaily
Aarẹ Ramzan Kadyrov naa ti wọnu saree Anọbi Muhammad ni mọṣalaṣi anọbi to wa ni Medina lọdun 2018 nibi ti awọn oṣiṣẹ Saudi ti gbalejo rẹ.
Ọdun 2007 ni Kadyrov to gori oye lẹyin baba rẹ di aarẹ Chechnya nigba to pe ẹni ọgbọn ọdun.
Awọn ọba ilẹ Saudi.

Oríṣun àwòrán, SPA
Awọn alaṣẹ sọ pe Ọba Abdulaziz ati Faisal ni wọn wa ninu iwe akọsilẹ awọn to ti wọ inu iboji saree Anọbi Muhammad (SAW) bi o tilẹ jẹ wipe Haramain Sharifain ṣalaye pe ọpọ ọba Saudi lo ti wọ ibẹ ṣugbọn ti ko si akọsilẹ rẹ ninu itan.
Aarẹ orilẹede Iran, Sayyid Muhammad Khatami

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Khatami ni aarẹ karun to jẹ lorilẹede Iran lọdun 1997 si 2005. Ohun si ni aarẹ Iran akọkọ ti yoo bẹ ọba ilẹ Saudi Arabia wo.
Lasiko naa ni wọn fi ṣi iboji saree Anọbi fun un, oun ni aarẹ karun ti yoo jẹ laarin ọdun 1997 si ọdun 2005.


















