COVID-19 in Lagos: Wo ìdí tó fi ṣeéṣe kí ìjọba àpapọ̀ ó kéde àkọ̀tun ìséde n'ipínlẹ̀ Eko

Aworan kokoro arun covid-19

Oríṣun àwòrán, other

Afaimọ ki ijọba apapọ o ma a tun gbe akọtun isede le ipinlẹ Eko lẹyin ti ijọba ipinlẹ naa kede pe awọn eeyan marundinlogoje ti sa kuro ninu ibudo ifiniwọsi fun ayẹwo COVID-19 ti wọn fi wọn si ni ilu Eko.

Awọn eeyan marundinlogoje naa wa lara awọn ero ọtalelẹẹdẹgbẹta ati mẹjọ arinrinajo ti wọn wọ Naijiria latawọn orilẹ-ede ti arun COVID-19 ti n ṣọṣẹ lagbaye to wọ orilẹ-ede Naijiria lẹnu lọwọlọwọ yii.

Awọn orilẹ-ede bii India, Brazil ati Turkey wa lara awọn orilẹ-ede ti awọn eeyan marundinlogoje naa ti wa ki wọn to juba ehoro kuro ni ibudo ifiniwọsi naa.

Kọmiṣọnna feto ilera ni ipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi ni o ṣepataki kawọn arinrinajo to salọ naa o tete gbe igbesẹ to tọ nipa ilana ti ijọba gbe kalẹ lati dẹkun itankalẹ arun naa.

Ọjọgbọ̀n Abayọmi fi kun pe ninu awọn marundinlogoje naa, mọkandinlọgọfa faake kọri pe awọn ko ni tẹle ilana ifiniwọ fun ayẹwo naa, mẹrindinlogun yooku si ti di awati.

Bakan naa lo ri awọn mọlẹbi awọn ti ọrọ naa kan lati pẹtu si awọn eeyan wọn ninu pe ki wọn pada bi wọn ko ba fẹ ki wọn foju wina ijiya gbogbo to rọ mọọ labẹ

O ni aitẹle ilana yii lee fa idajọ ẹwọn gẹgẹ bi ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ṣe gbe ofin kalẹ fun amofinagba rẹ lati tẹle.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Ẹgbẹrun marundinlẹẹdẹgbẹta o le diẹ ni iye ayẹwo arun COVID-19 ti wọn ti ṣe ni ipinlẹ Eko, ẹgbẹrun mọkandinlọgọta o din diẹ ninu wọn layẹwo fihan pe o laarun naa.

Ninu wọn ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta o le diẹ ninu wọn lara wọn ti ya, ọdunrun o le mẹrindinlọgọta lo ku ninu wọn.

Kọmiṣọnna feto ilera ni ipinlẹ Eko naa ṣalaye pe ijọba ipinlẹ Eko ati ajọ irinna ofurufu ni Naijiria, FAAN ti gbe ilana kalẹ ti yoo mu irinajo rọ awọn arinrinajo lọrun.

Eyi yoo jẹ nipa pipese awọn ile igbafẹ ti wọn fọwọsi tawọn arinrinajo to ṣẹṣẹ wọle lee wọ si fun eto ifiniwọsi fun ayẹwo COVID-19 wọn.

Àkọlé fídíò, Adebayo Murital David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

Ijiya to wa fun arinrinajo to ba kuna lati tẹle ilana ifiniwọsi fun ayẹwo COVID-19.

  • Gbogbo awọn ti ọrọ naa kan ni wọn yoo gbẹsẹle iwe irinna silẹokeere wọn
  • Bi wọn ba jẹ ajeji, ijọba yoo wọgile iwe igbelu wọn, wọn yoo si le wọn kuro ni Naijiria
  • Lilọ si ẹwọn labẹ ofin to gbogunti itankalẹ arun COVID-19 nipinlẹ Eko ati owo itanran to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira.