Ibadan Robbery: Adigunjalè ja Ọ̀gá ọlọ́pàá àti ẹni mẹ́ta míràn lólè

ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, @NPF

Gọngọ sọ ni ilu Ibadan nibi ti ọpọ ti lanu silẹ pe ori ki lo wa lori atẹ yii?

Awọn adigunjale ya bo Alaafia Estate ni nnkan bii ọsẹ meji ṣeyin ti wọn si ja ọga ọlọpaa kan atawọn eeyan mẹta mii lole lagbegbe ọhun.

Lẹyin naa ni wọn tun ṣabẹwo si agbegbe ọhun lẹẹkan si lati ja awọn olugbe ibẹ lole.

Bi wọn ṣe ji oriṣiriṣi dukia naa ni wọn tun ji kaadi ATM awọn olugbe ọhun lọ.

Àkọlé fídíò, Adebayo Murital David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

Bẹẹ, awon Adigunjalè bíi ogun yii kọlu adúgbò Alaafia Estate nílùú Ibadan pẹ̀lú ẹ̀rọ POS

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe lootọ ni awọn adigunjale ti iye wọn to ogun kọlu ọgba Alaafia Estate to wa lagbegbe Orogun niluu Ibadan, ti wọn si ko awọn dukia olowo iyebiye lọ.

Iroyin ni awọn adijale ọhun ya bo agbegbe naa pẹlu ẹrọ ipọwo POS lọwọ wọn lati fi gba owo lọwọ awọn eeyan adugbo naa.

Ngozi Onadeko

Oríṣun àwòrán, @Gidi_Traffic

Iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bii aago mọkanla aṣalẹ, ti wọn si ṣọṣẹ titi di nnkan bii aago meji oru.

Lara awọn dukia ti wọn sọ pe awọn adigunjale naa ko lọ ni ẹrọ kọmputa alagbeka, ẹrọ ilewọ ati owo.

Adigunjalè bíi 20 kọlu adúgbò Alafia Estate nílùú Ibadan pẹ̀lú ẹ̀rọ POS, wọ́n kó ọ̀pọ̀ dúkìá lọ

Awọn adigunjale ọhun wọ adugbo naa lati oju ọna odo kan ti ijọba ṣẹṣẹ gbẹ, eyii to so mọ agbegbe Barika, Agbowo ati Orogun.

Lara awọn ohun ija ti wọn ko dani ni ada, ibọn atawọn ohun ija oloro miran.

Iroyin ni ko din ni ogun idile ti awọn adigunjale ọhun ya ojule wọn lasiko ti wọn ṣọṣẹ.

Bo tilẹ jẹ wọn gbe ẹrọ POS lọwọ lati gba owo ninu apo ifowopamọsi awọn eeyan naa, iroyin ni wọn ko ọpọ kaadi ATM lọ nitori nẹtiwọọki to kọṣẹ.

Bakan naa ni wọn tun ba dukia awọn idile kan jẹ lẹyin ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn n yọju wo awọn lasiko ti wọn n ja awọn alabagbe wọn lole.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Adewale Osifeso ni lootọ ni awọn gba ipe pajawiri lati adugbo Alaafia Estate.

O ni nnkan bi aago mẹta oru ni awọn oṣiṣẹ awọn lọ si adugbo ọhun, ṣugbọn awọn alọ kolohun kigbe naa na papa bora ni kete ti wọn ri awọn.

O pari ọrọ rẹ pe iṣẹ ti bẹrẹ lati fi ṣikun ofin mu awọn adigunjale ọhun.

Àkọlé fídíò, Bode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka