China Child Birth: Ẹ̀yin lọ́kọ-láya kò gbọdọ̀ bí ju ọmọ mẹ́ta lọ lásìkò yìí - Ìjọba China

Oríṣun àwòrán, EPA
Ijọba orilẹ-ede China ti kede pe awọn tọkọ-taya ti ni anfaani lati maa bi ọmọ mẹta bayii dipo meji ti wọn faye gba wọn lati maa bi tẹlẹ.
Wọn gbe igbesẹ yii nitori bi iye ọmọ ti wọn n bi lorilẹ-ede naa ṣe n dinku si lọdọdun.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ sọ pe awọn lọkọ-laya ko gbọdọ bi ju ọmọ kan lọ nitori bi iye ero to wa lorilẹ-ede ọhun ṣe burẹkẹ sii.
- Omoyele Sowore dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tó fara gba ọta gáàsì tajútajú l'Abuja
- Ọkọ àti ìyàwó ri ọmọ ọdún kan àbọ mọlẹ láàyè lọgànjọ oru, àṣírí tú!
- Ọjọ́ kínní oṣù kẹfà ni Amotekun yóò bẹ̀rẹ̀ sí ni máa gbógun tàwọn ọ̀daràn àti ajínigbé nílẹ̀ Yorùbá
- Wo ìdí tí ECOWAS fi dá Mali dúró, tó tún fún àwọn ológun ní gbèdéke láti gbé ìjọba sílẹ̀
Ṣugbọn nigba to di ọdun 2016 ni wọn yii aṣẹ naa pada ti wọn si bẹrẹ si n faye gba ki awọn tọkọ-taya ni ọmọ meji.
Igbeṣe tuntun yii lo waye lẹyin ti Aarẹ Xi Jinping buwọlu aṣẹ tuntun ọhun, eyii to faye gba awọn obi lati le bi ọmọ to mẹta.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yatọ si aṣẹ ijọba, o ṣoro fun ọpọ idile lati tọju ọmọ bẹẹrẹ nitori bi eto ọrọ aje ṣe ri nilẹ naa lasiko kan.
Ileeṣẹ iroyin Xinhua jabọ pe "Ijọba yoo ṣe atilẹyin fun awọn lọkọ-laya lọna ati mu afojusun orilẹ-ede naa ṣẹ."
Ẹwẹ, ajọ ajafẹtọ ẹni lagbaye, Amnesty International ti sọ pe aṣẹ tuntun naa ati eyii to ti waye ṣaju rẹ ko bojumu to.
Amnesty International ni ẹtọ araalu ni ki wọn bi ọmọ bi wọn ṣe fẹ lai si amojuto kankan lati ọdọ ijọba.
Wọn sọ pe "Ijọba ko ni ẹtọ kankan lati maa ṣe akoso iye ọmọ ti eeyan le bi, o yẹ ki ijọba China bọwọ fun ẹtọ awọn araalu lati gbe igbeaye wọn bi wọn ṣe fẹ."
- Nǹkan bíi ọmọ ilé kéú 150 ni àwọn agbébọn jí gbé lọ ní Niger
- Ẹ̀mí àìrí lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde ni ilé ẹ̀kọ́ St Claire's ní Offa
- Ọjà olówó iyebíye jóná nínú ọjà Ladipo nílùú Eko
- Kí ló bí ìsinmi tí àwọn ajìjàngbara Biafra kéde fáwọn Ibo láti ṣ'àyájọ́ Biafra?
- Àwọn jàndùkú agbébọn ṣekúpa Ahmed Gulak, olùdàmọ́ràn Goodluck Jonathan















