Zamfara: Ìdí tí a fi mú àwọn olùfẹ̀hónúhàn lórí pé wọ́n tẹ òfin ètò ààbò lójú.

Zamfara: Ìdí tí a fi mú àwọn olùfẹ̀hónúhàn lórí pé wọ́n tẹ òfin ètò ààbò lójú.

Oríṣun àwòrán, Police

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Zamfara ti kéde pé àwọn mú àwọn olùwọ́de ìfẹ̀hónúhàn kan tó jẹ́ olùgbé agbègbè ìlú Kuryar Madaro níjọba ìbílẹ̀ Namoda.

Wọ́n mú wọn nítórí pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwọ́dé ìfẹ́hónúhàn lọ́jọ́ ajé láti pé àkíyèsí àwọn aláṣẹ́ ìjọba sí ètò àbò tó mẹ́hẹ.

Ìròyìn sọ pé àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà dí ojú pópó tó tóbi jùlọ ni agbègbè náà tí ọkọ̀ kanakan kò le gba ibẹ̀ kọ́ja pẹ̀lú ìlérí pé àwọn kò ni sinmi títí tí nńkan yóò fi yípadà.

Gẹ́gẹ̀ bi agbẹnusọ àwọn ọlọ́pàá Muhammad Shehu ni agbègbè náà ṣe sọ, àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà ń di àbójútó ètò ààbò lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ náà.

Ó sàlàyé pé nǹkan tí kò ṣẹlẹ̀ ni àwọn ènìyàn ń gbé kiri àti pé ọ̀pọ̀ ni kò fẹ́ àlááfíà, àwọn ọlọ́pàá ṣí ọ̀nà tí àwọn olùfẹ̀hónúhàn dí láti jẹ́ kí àwọn ará ìlú máá bá iṣẹ́ òòjọ́ wọn lọ.

"Láàrín àwọn olùfẹ̀hónúhàn ni a ti gba ìbọ̀n ìbílẹ̀ ńlá kan tí wọ́n fí n dẹ̀rúba àwọn ènìyàn .

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Sáájú ní àwọn ará ìlú tí sọ fún BBC pé, ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn náà kò ṣẹ̀yìn bi àwọn ọlọ́pàá ṣe ketí ikún sí àwọ ẹsùn tí àwọn ń mú lọ fún wọ́n lórí ọ̀rọ̀ àbò.

" Ó ti lé ní ọjọ́ mọ́kànlélógún tí a tí n dàmú bí àwọn olè ṣe wá n yọ wá lẹ́nú ní abúlé yìí, a bèrè fún ìrànlọ́wọ́ ọlọ́pàá sùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti rànwá lọ́wọ́." èyí ni nǹkan ti àwọn olùgbé náà sọ.

Ó ní àwọn kò ní sinmi ìfẹ̀hónúhàn títí ìjọba yóò fi dá àwọn lóhùn.

Àkọlé fídíò, Adebayo Murital David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

Ẹ̀wẹ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti sọ fún àwọn ará ìlú láti mú ẹsùn wà tí òhunkóhún bá ṣẹ̀lẹ̀ lágbègbè wọn.

Láípẹ̀ yìí ní àwọn ènìyàn Dan Saadu ní ìpínlẹ̀ Zamfara tí ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ọlọ́jọ́ kan ti ọkọ̀ kò sí rìn nítori bi ìkọlu àwọn olè ojú ọmí ṣe n pọ̀ sì.