Oluwo 5th coronation anniversary: Èyí ni àwọn ìgbà mẹ́jọ tí ọ̀rọ̀ Oluwo di ariwo nígboro láàrín ọdún márùn ún rẹ̀ lóyè

Oluwo n gba ọpa aṣẹ ati iwe ẹri lọwọ gomina ipinlẹ Ọṣun nigba naa, Rauf Arẹgbẹṣọla

Oríṣun àwòrán, osun state government

Ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kini ọdun 2016 ni wọn fi Ọmọọba Abdulrasheed Akanbi jẹ oye gẹgẹ bi Oluwo ti ilu Iwo, oun si ni Ọba kẹrindinlọgbọn ti yoo joko lori itẹ naa.

Idile Oye Gbaase ni Oluwo Abdulrasheed Akanbi ti ṣẹ jade wa, ilu Canada lo si wa to ti n ṣe iṣẹ Kọngila ki wọn to fi jẹ Ọba lẹyin ọdun meji ti Oluwo ana, Ọba Ashiru Tadeṣe ti waja.

Lati igba to si ti de ori ipo, orukọ Kabiyesi Abdulrasheed Akanbi kii wọn loju ewe iroyin, ni ọpọ igba lo si maa n jẹ nitori awon ohun to ni ariwisi kan tabi omiran.

Idi niyi ti a fi n gbe awọn iṣẹlẹ manigbagbe to ti waye laarin ọdun marun Oluwo ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi nipo.

Wiwọ aṣọ oyinbo pẹlu ade ilu Iwo lori itẹ.

Oluwo tilu Iwo

Oríṣun àwòrán, oluwo

Lootọ awọn ọba kii ṣe angẹli, ṣugbọn ipo to lagbara ti ko si yẹ ko ni aleebu kankan ni awọn Yoruba to wọn si, idi si niyi ti wọn fi maa n fi oju igbakeji Olodumare wo wọn.

Nigba ti Ọba Akanbi kọkọ de ori itẹ lara awọn ariwisi to kskọ jade sii ni bi o ṣe n wọ awọn aṣọ oyinbo si abẹ ade ilu Iwo lori itẹ ilu Iwo. Eyi da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ nigba naa nitori oju kotọ ni ọpọ onwoye atawọn ọmọ ilẹ kaarọ oojiire fi wo eyi nigba naa.

Gbogbo awijare ti kabiyesi Oluwo si n fi sita lori igbesẹ naa nigba naa ni ko tẹ awọn eeyan lọrun, ki o to di wi pe o tun ọrọ naa ṣe nigba naa.

Sisọ ara rẹ di Emir

Oluwo n ba awọn eeyan ilu Iwo sọrọ

Oríṣun àwòrán, oluwo of iwo/twitter

Ni ọdun 2018 ni Oluwo kede pe oun gangan ni Emir ilẹ Yoruba lasiko ti wọn fi n ṣe ayẹyẹ iwe-lawani fun Fadhilaru Sheikh Yahquub Abdul-Baaqi Mohammed gẹgẹ bii Waziri ilẹ Yoruba.

"Emi ni Emir Yoruba.

Niwọn igba ti alaafin Ọyọ ba laṣẹ lati yan Aarẹ Ọna kakanfo ati Iyalode ilẹ Yoruba, Emi naa ni agbara ati aṣẹ lati yan Waziri fun ilẹ Yoruba gẹgẹ bi itan ṣe fi idi rẹ mulẹ pe Oluwo ni ọba akọkọ to gba ẹsin Islam ni ilẹ Yoruba."

Eyi fa ọpọ faa sihin, faa-sọhun nigba naa eleyi to mu ki ọpọ tilẹ pariwo si ọbalaye naa nigba naa pe boya ko kuku gbe ade Iwo silẹ ko gba oke ọya lọ lati lọ jẹ Emir rẹ to fẹ jẹ.

Ṣiṣiwaju irun ati Wahala pẹlu Imam agba ilu Iwo ni yidi.

Oluwo n kirun ni yidi kan

Oríṣun àwòrán, oluwo of iwo/twitter

Lara awọn agbọgbọntinu iroyin ariwisi to so mọ Oluwo Abdulrasheed Aknbi leti aṣọ laarin ọdun ọdun marun un rẹ loye ni ti ọrọ ẹsin ni ilu Iwo.

Akọkọ, ni bi o ṣe lewaju gbigbe irun dide lasiko irun yidi kan ni ilu Iwo eyi ti awọn ẹlẹsin Musulumi ni ilu naa ati nibomiran bu ẹnu atẹ lu pe o kyu diẹ kaato nitori ojuṣe awọn Imaamu lo fẹ gbaṣe bẹẹ.

Ko pẹ ti Oluwo Akanbi de ori itẹ ti Iṣẹlẹ yii fi ṣẹ nigba naa lọdun 2016. Oluwo funrarẹ si ni oun ni olori ẹsin ni ilu Iwo, nitori naa oun laṣẹ lati gbe irun dide tabi lewaju adura ni yidi. Ọpọ awọn onimọ ẹsin Islam nigba naa lo si sọ wi pe Oluwo Abdulrasheed Akanbi ko ni gbogbo ilana ati ẹtọ ti o yẹ fun ẹni to lee ṣiwaju adura bẹẹ.

Lẹyin eyi ni wahala tun bẹrẹ laarin oun ati Imaamu agba Mọṣalaṣi ilu Iwo, Sheihk Adio. Koda wọn gbe aawọ yii de ori irun yidi nibi ti Imaamu naa ti fi ẹsun kan Oluwo Akanbi pe o gbimọnran ati ba iyawo oun lajọṣepọ.

Bi o tilẹ jẹ wi pe Kabiyesi Oluwo ni ko sohun to jọ bẹẹ, sibẹ ọpọ lo pariwo sita pe irufẹ eyi ko ṣee maa gbọ seti si ọbalaye.

Gbigbe ade le olori rẹ, Chanel Chin lori pẹlu ija ajatuka to pada waye laarin wọn.

Oluwo ati aya rẹ tẹlẹ, Chanel Chin

Oríṣun àwòrán, oluwo/twitter

Lootọ ni awọn agba bọ ti wọn ni ko si apọnle fun ọba ti ko ni olori. Amọṣa, Ọba Akanbi ṣe eyi to le kenka ni tirẹ nipa gbigbe ade le olori rẹ lori.

Ninu itan Yoruba, ko fẹẹ tii si ọba kan to gbe ade le iyawo rẹ lori ri. Idi ni pe Yoruba gbagbọ pe ko si idi fun ade meji lati wa ninu ilu kan naa lẹẹkan ṣoṣo.

Amọṣa o, Oluwo ti ilu Iwo gbe ade le Chanel Chin aya rẹ lori. O ni idi ti oun fi ṣe bẹẹ ni pe Oduduwa to jẹ baba Yoruba gbe ade le iyawo rẹ, Olokun lori.

Ohun ati aya rẹ naa ja ajatuka loṣu kejila ọdun 2019 eleyi to tun tu oniruuru ẹgbin sita.

Wahala pẹlu Ọọni ile Ifẹ

Oluwo ati Ooni ile Ife N ki ara wọn

Oríṣun àwòrán, oluwo/twitter

Lootọ, nigba ti Oluwo n gori itẹ, Ọọni ile Ifẹ Adeyẹye Ogunwusi ti dade ni ile Oodua, ṣugbọn ọrẹ ati kekere wa ni wọn pe awọn mejeeji.

Amọṣakini ọhun yipada lẹyin asiko diẹ. Oniruuru idi lawọn eeyan n gbe dide fun ohun to le faa aawọ laarin awọn ọbalaye mejeeji yii.

Aawọ naa n lọ labẹnu fun ọpọlọpọ igba ki o to bẹ lu sita fun araye nibi eto ipade awọn lọbalọba kan to waye ni ipinlẹ Rivers nibi ti Oluwo ti fẹsun kan Ọọni pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ alaabo rẹ lu oun.

Oluwo ni Ọọni ile Ifẹ lo paṣẹ fun oṣiṣẹ rẹ naa lati ti oun. Eleyi fa ọpọlọpọ ariwisi nigba naa debi wi pe awọn oloye Iwo kan tilẹ koro oju si Oluwo ti wọn si ni ko tọwọ ọmọ rẹ bọṣọ.

Oluwo gba Ọba ẹgbẹ rẹ ni ikuuku, awọn ọba ipinlẹ Ọṣun ba baa wi

Oluwo n ju san eeyan ilu Iwo

Oríṣun àwòrán, oluwo/twitter

Afi bii pe iran ariwisi Ọba Abdulrasheed Akanbi ko tii to nkan lọrọ ri ni ọdun 2020 nigba ti iroyin jade si igboro pe Ọbalaye naa lu Agbowu ti Ilu Ọgbaagbaa, Ọba Dhikrulahi Akinrọpo lasiko ipade ipẹtusaawọ kan laarin awọn ọbalaye ni ijọba ibilẹ Iwo ati Ọla-Oluwa.

Bi o tilẹ jẹ wipe Oluwo ni ọrọ kobakungbe ti Agbowu n sọ si oun lo ṣokunfa dundu iya ti oun din fun un jẹ niwaju ọga ọlọpaa ẹkun kọkanla, Zone 11 lọjọ naa.

Eyi ko dun mọ ọpọ ọmọ Yoruba ninu rara ti wọn si bu ẹnu atẹ lu iwa yii.

BBC News Yoruba gbe iroyin naa jade nigba naa

Àkọlé fídíò, Ki lo fa Ija lọbalọba ni ilu Iwo

Igbiyanju ati rọọ loye

Oluwo n ba awọn eeyan ilu Iwo sọrọ

Oríṣun àwòrán, facebook/emperor Abdulrasheed Adewale Akanbi telu

Awọn agba oye ilu Iwo kan pe birikoto ni ọdun 2020 lati yọ oluwo Akabi. Ko si idi meji ju awọ n ariwisi ti o n wọ tọọ lẹyin eleyi ti wọn ni o n ta ẹrẹ ba Itẹ ilu Iwo.

Awọn afọbajẹ mejila naa kọwe ẹhonu si gomina Oyetọla pe Ọba Abdulrasheed Akanbi ko ṣojuṣe rẹ gẹgẹ bi Oluwo daadaa.

Lara awọn ẹsun loniraanran ti wọn si ka sii lẹsẹ ni "ẹsun ṣisafojudi si Ọọni ile Ifẹ, ija to ba Imaamu Adio ja, Alaafin Ọyọ ati Ọrangun Ila"

Pinpin awọn ohun amayedẹrun fun arugbo atawọn alaini.

Oluwo n fun awọn arugbo kan ni owo

Oríṣun àwòrán, facebook/emperor Abdulrasheed Adewale Akanbi telu

Lara awọn ọba to ni ifẹ awọn alaini ati arugbo ni Oluwo wa. Eyi si tubọ jẹyọ lasiko ti ajakalẹ aarun Coronavirus jade sita lọdun 2020.

Lara awọn Ọba to mu idẹrun tọ awọn eeyan wọn paapaa nipa pinpin ohun jijẹ ati mimu fun awọn alaini ati arugbo ilu ni Oluwo Akanbi wa.

Ọpọ igba ni Ọbalaye yii si maa n wọ inu ilu tọ awọn ti ko ni lọ atawọn arugbo lati ṣe itọrẹ aanu fun wọn, eyi mu ọpọlọpọ awọn mẹkunu ilu Iwo o fẹran rẹ pẹlupẹlu gbogbo ariwisi to n wọ tọ ọbalaye naa lẹyin.