Uganda elections 2021: Ààrẹ Yoweri Museveni ló jáwé olúborí ìdìbò ààrẹ ní Uganda

Oríṣun àwòrán, AFP
Aarẹ to tí n ṣe ijoba bọ lati ọdún marundinlogoji lorilẹede Uganda, Yoweri Museveni lo tun pegede ninu idibo ààrẹ to waye nilẹ naa gẹgẹ bi awọn eleto idibo ti ṣe kede.
Ikede yi nwaye toun ti pe awọn alatilẹyin oludije aalatako Bobbi Wine fẹsun kan wọn pe orisirisi magomago lo waye ninu idibo ọhun.
Ajọ eleto idibo ni Ọgbẹni Museveni ri to ibo ida mọkandinlọgọta 59% ninu ida ọgọrun ti alatako rẹ Ọgbẹni Wine si ri ida marundinlogoji ibo tii ṣe 35%.
Ṣaaju ni ọgbẹni Wine to jẹ akọrin takasufe ti leri lati ṣàfihàn ẹri makaruru to waye ninu idibo naa.
Amọ ajọ ọhun sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ ninu ibo to waye lọjọbọ.
Awọn to n woye eto idibo naa bẹnu àtẹ lu bi ijoba ti ṣe gbegi dina ojú òpó ayelujara nilẹ naa lasiko idibo.
Wọn ni igbesẹ yi ko je ki awọn eeyan ni igbagbọ ninu eto idibo to waye
- Ẹ wo ọba kan nílẹ̀ Yorùbá, tí kò ṣe ètùtù tàbí náwó ànájù, kó tó jọba
- Ààrẹ Museveni tó ti ṣèjọba Uganda fọ́dún márùnlélọ́gbọ̀n(35) ló ń léwájú nínú ìbò ààrẹ ilẹ̀ náà
- "Olórí àwùjọ tó ń fi eékà ilẹ̀ pààrọ̀ fún màálù torí ìnáwó ló jẹ́ ki darandaran rọ̀wọ́ mú"
- Dókítà 66 síṣẹ́ abẹ fún ìbejì tó lẹ̀pọ̀ nílé ìwòsàn fasiti Ilorin
- Wo àwọn ààrẹ Amẹ́ríkà mẹ́rin tí wọn rọ̀ lóyè àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn
Bakan naa ni ọgbẹni Wine sọ pe kete ti anfaani ayelujara ba sì silẹ pada òun yoo mu ẹri wa lati fi jẹri ọrọ rẹ.
Ọgọrọ eeyan lo padanu ẹmi wọn ninu ikọlu to waye ṣaaju idibo.
Bẹẹ naa ni awọn alatako ni ijọba n dun koko mọ awọn.
Pẹlu esi yi aarẹ Museveni yoo ṣe ijoba fún saa kẹfà ni ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin.
Ààrẹ Museveni tó ti ṣèjọba Uganda fọ́dún márùnlélọ́gbọ̀n(35) ló ń léwájú nínú ìbò ààrẹ ilẹ̀ náà
Ẹnikan kiki jẹ, ki ilẹ o fẹ lawọn Yoruba maa n wi. Amọ bi ti aarẹ prilẹede Uganda, Yoweri Museveni kọ o.

Oríṣun àwòrán, EPA
Aarẹ Museveni to dije fun ipo aarẹ fun saa kẹfa ninu idido Ọjọbọ lo lewaju gẹgẹ bi awọn esi ibo ti wọn ti ṣe sọ.
Oludije fẹgbẹ oṣelu alatako to ti figba kan jẹ akọrin ri, Bobi Wine ni eeru pọ ninu eto idibo ọhun, ati pe niṣe wọn yi ibo rẹpẹtẹ.
- Irọ́ ni pé ọba tuntun má a ń jẹ ọkàn ọba tó bá wàjà ní ìpèbí - Elebuibon
- Wo bí ìyàwó ṣe le gbé ọmọ Ọbà fún Ọ̀ṣun láì yan àlè
- Ẹ wo ọba kan nílẹ̀ Yorùbá, tí kò ṣe ètùtù tàbí náwó ànájù, kó tó jọba
- Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
- Ẹlẹ́tàn ni ọkùnrin, tó bá rí nkan tó n wa lára obìnrin, yóò yí ìwà padà - Bimpe Oyebade
- Wo ẹ̀kọ́ mẹ́rin tí Naijiria kùnà láti kọ́ lára ogun abẹ́lé
- Dókítà 66 síṣẹ́ abẹ fún ìbejì tó lẹ̀pọ̀ nílé ìwòsan fasiti Ilorin
Awọn onwoye to tẹle eto idibo naa sọ pe ẹrọ alatagba to dẹnu kọlẹ fun ọjọ mẹta ni Uganda ko jẹ ki awọn eeyan ni igbagbọ ati igboya ninu eto idibo naa.
Ṣugbọn ileeṣẹ eleto idibo sọ pe ko si ohun to jọ eeru tabi magomago ninu eto idibo naa.
Ọjọ Abamẹta tii ṣe ọjọ kẹrindinlogun oṣu kinni ọdun 2021 yii ni esi ibo to ku yoo jade.
Ọpọ eeyan lo ku lasiko rogbodiyan to ṣẹlẹ ni Uganda ṣaaju eto idibo aarẹ.
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako tun ti fi ẹsun idunkoko mọ ni kan ijọba ilẹ naa.
Aarẹ Museveni ti n ṣe ijọba orilẹede Uganda fun ọdun marundinlogoji bayii.
Oludije fẹgbẹ osẹlu alatako, Robert Kyagulanyi ti orukọ inagije n jẹ Bobi Wine figbe ta lọjọ Ẹti nigba ti esi ibo bẹrẹ si ni jade pe awọn sọja rọgba yi ile oun ka.
Amọ, agbẹnusọ fun ijọba, Don Wanyama ni asọdun lasan an ni Wine n sọ.
Wanyama ṣalaye pe eeyan pataki ni Wine jẹ lasiko yii, iyẹn lo jẹ ki ijọba ni kawọn ẹṣọ wa nile rẹ fun abo to muna doko.












