Trump Impreachment: Donald Trump, Bill Clinton ati Richard Nixon

Oríṣun àwòrán, Alamy
Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump ti di Aarẹ akọkọ ti Ile Igbimọ Aṣofin yọ kuro nipo lẹẹmeji ọtọọtọ.
Eleyii ti mu aarẹ Trump darapọ mọ awọn aarẹ to ti jẹ lorilẹede Amerika ri, ti wọn si ti yọ nipo.
Nkan to ṣẹlẹ si awọn aarẹ naa ree:
Andrew Johnson

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arakunrin Andrew Johnson ni aarẹ akọkọ lorilẹede Amerika ti Ile Igbimọ Asofin yoo dibo lati yọ kuro ni ipo.
Ki ni ẹsẹ rẹ?
Lasiko ogun abẹle ni orilẹede Amẹrika, ni Aarẹ Andrew Johnson to jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu Democrat, fi ori gbari pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republicans to jẹ awọn lo pọju ninu Ile Igbimọ Asofin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ẹ̀kọ́ mẹ́rin tí Naijiria kùnà láti kọ́ lára ogun abẹ́lé
- Dókítà 66 síṣẹ́ abẹ fún ìbejì tó lẹ̀pọ̀ nílé ìwòsan fasiti Ilorin
- Àwọn agbébọn tó ń gba ojúgbó wọlé máa ń tó 1000 lẹ́ẹ̀kan náà - Amotekun
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún míì tí kò bá ti sọ Nàíjíríà sínú ogun abẹ́lé kejì
- Ọlọ́pàá kò fẹ́ yìnbọn, kó má ba à ba aráàlú, l‘àwọn afurasí olóògùn olóró ba sá mọ́ wọn lọ́wọ́
- Ẹ má ṣùn àṣùnpiyè o! Àwọn àjèjì darandaran ń wọ ìpínlẹ̀ Oyo àti Ogun lọ́gọ́ọ̀rọ̀ - Amotekun
- Covid-19 pa Ọlọ́lá Akin Olugbade, ẹ wo dúkìá jaburata tó fisílẹ̀
- NCDC àti NYSC bẹ̀rẹ̀ ìpàdé lórí ṣíṣí ìpàgọ́ àwọn àgùnbánirọ̀
- Ìjọba ìpińlẹ̀ Kwara dá owó tí àwọn obìrin 25 fi kọ́ ilé Ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ wọ́n pada
- Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ kí ilé-ẹ̀kọ́ wọlé ní ọjọ́ 18, oṣù kíní ọdún.
Ohun to fa ija wọn ni ọrọ lati ṣe atunṣe iha Guusu orilẹede Amerika ti o ti bajẹ nitori ogun abẹle naa.
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republicans kan nigba naa, parapọ lati fi iya jẹ awọn to jẹ adari tako iṣọkan ilẹ Amẹrika.
Eyi lo wa lati daabo bo ẹtọ awọn ẹru ti wọn tu silẹ, amọ aarẹ Johnson lo agbara rẹ lati gbegile igbese ẹgbẹ Democrats yii.

Oríṣun àwòrán, Library Of Congress
Bakan naa ni Aarẹ Johnson tun kọ fun awọn aṣofin lati dena isẹlẹ naa lasiko to fẹ yọ ọkan lara awọn minisita rẹ to jẹ ọta rẹ, iyẹn Edwin Stanton lasiko ti ile Aṣofin lọ fun isinmi.
Yiyọ ti wọn yọ Johnson mu ki awọn ọmọ Ile Aṣofin gbe igbesẹ lati yọ aarẹ naa ni ipo.
Lẹyin idibo ile igbimọ Aṣofin kekere, ti wọn si yọ nipo, amọ ile Aṣofin agba fi silẹ nitori idibo naa ku eniyan ẹyọ kan ko pe ida mẹta ti wọn nilo lati yọ kuro nipo gẹgẹ bi aarẹ.
Kini ipalara iyọkuro fun Andrew Johnson?
Iroyin kan sọ wi pe, Johnson dubulẹ to si sunkun nigba ti o gbọ pe Ile Igbimọ Aṣofin Agba ti dena iyọkuro nipo rẹ.
Johnson jẹjẹ lati ṣe daradara ju ti tẹlẹ lọ, amọ pabo lo jasi nitori awọn ọta rẹ si duro sibi ati subu rẹ.
Ni ọdun 1869 ni ẹgbẹ oṣelu Democrats kuna lati di ipọ aarẹ mu, ti oludije lẹgbẹ oṣelu Republican, Ulysses S Grant si gba ijọba.
Kini awọn ohun ti Andrew gbeṣe ni asiko rẹ?
- Won yọ ọ nipo aarẹ
- O ra Alaska ni ọdun 1867 fun miliọnu meje o le, ni iye owo dọla ile okeere
- Johnson nigba aye rẹ jẹ ọkan lara awọn aarẹ to talaka julọ, ti ko si lọ si ileewe.
Richard Nixon:

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdun 1972 ni wahala de fun Aarẹ Richard Nixon, lẹyin ti wọn ṣekọlu si olu ileeṣẹ ẹgbẹ Democrats to wa ni Watergate ni Washington DC.
Lẹyin naa ni iwadii fihan pe, owo eto idibo to gbe Nixon wọle, ni wọn san fun awọn adigunjale to ṣe ikọlu si Watergate naa, ti o si fa akọba fun awọn oṣiṣẹ Ile Ijọba, White House.
Fun ọdun meji gbako ni Nixon fi tiraka lati pana ẹsun naa, amọ ko ṣeeṣe, to si jasi ijakulẹ rẹ.
Ni ọdun 1974 ni ile aṣofin bẹrẹ igbeṣẹ lati yọ nipo, lẹyin ti iwadii fi ohun Nixon han, nibi ti o ti n sọ fun oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ CIA lati da ọwọ iwadii ikọlu Watergate duro.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi o tilẹ jẹ wi pe Ile Igbimọ Aṣofin tiraka lati dibo yọ nipo, amọ ko waye.
Nixon ni Oṣu Kẹjọ, ọdun 1974 kọwe fi ipo silẹ, oun si ni aarẹ orilẹede Amerika ti yoo kọwe fi ipo silẹ.
Kini ipalara fifi ipo silẹ fun Nixon?
Igbakeji aarẹ, Gerald Ford lo gba ipo aarẹ lẹyin ọsẹ mẹfa ti Nixon fi ipo silẹ.
Bakan naa ni wọn dari gbogbo ẹṣẹ rẹ jin lasiko to wa ni ipo.
Amọ ẹgbẹ oṣelu Republican kuna lati bori ninu idibo sipo aarẹ to waye ni ọdun meji lẹyin iṣẹlẹ naa.
Jimmy Carter ti ẹgbẹ oṣelu Democrat lo rọpo rẹ gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Amẹrika.
Kini awọn ohun manigbagbe to ṣe?
Ko si ohun miran to fa ijakulẹ rẹ yatọ si wahala Watergate naa, amọ o yari pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.
Ọdun 1994 ni Nixon jade laye, lẹyin ogun ọdun to fi ipo silẹ nitori ẹsun iwa ipa ti wọn fi kan an.
Ohun ti Aarẹ Bill Clinton sọ lasiko to n sọrọ lẹyin iku rẹ ni wi pe, ki awọn eniyan dari gbogbo ẹsẹ rẹ ji i, ki wọn si ye sọrọ rẹ ni aida mọ.
Bill Clinton

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ọdun diẹ ti Bill Clinton parọwa si awọn eniyan lati dariji Nixon ni wahala tun suyọ fun oun naa.
Clinton to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democrat ni wọn bẹrẹ si ni ṣe iwadii rẹ lẹyin ọdun kan to de ipo aarẹ.
Ohun ti wọn n se iwadii rẹ le lori ni wi pe, o ra awọn ile kan ni idakọnkọ ati ẹsun ifipabanilopọ laarin rẹ ati Monica Lewinsky, to jẹ oṣiṣẹ ile Ijọba, White house.
Lẹyin iwadii ọlọjọ gbọọrọ, Clinton ni irọ ni wọn pa mọ oun, ati pe oun ko jẹbi ẹsun ifibanilopọ ti wọn fi kan oun nitori oun ko ni ibalopọ pẹlu Monica.
Awọn aṣofin dibo lati yọ Clinton nitori awọn ẹsun ti wọn fi kan an yii, amọ ile aṣofin agba tu Clinton silẹ lati ma a lọ lalafia.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kini ipalara fun Bill Clinton?
Fun odidi ọdun kan ni ẹsun ifipabanilopọ laarin Lewinsky ati Clinton gba orilẹede Amẹrika kan.
Amọ, lasiko yii gan ni awọn eniyan dibo fun pe awọn ni igbagbọ ninu rẹ fun ju atẹyinwa.
Iroyin fihan pe ida mẹtadinlaadọrin ọmọ Ilẹ Amerika lo dibo pe awọn fi ọwọ si Clinton gẹgẹ bi aarẹ Amẹrika.
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republicans nikan lo padanu iṣẹ wọn, ti wọn si tun padanu awọn idibo ti wọn ṣe ni awọn ilu kọọkan.

Oríṣun àwòrán, NewYork Times
Ọdun 2001 ni Clinton kuro ni ipo aarẹ, amọ ẹgbẹ oṣelu rẹ kuna lati bori gẹgẹbi aarẹ, ti George Bush si di aarẹ ilẹ Amẹrika lẹyin rẹ.
Kini awọn ohun manigbagbe ti Clinton ṣe?
Ohun to leke tente lasiko iṣejọba rẹ ni ẹsun ifipabanilopọ pẹlu Monica Lewinsky.
Ati igbiyanju lati yọ nipo ti ko ṣeeṣe
Bakan naa ni igbagbọ ti awọn eniyan ni ninu rẹ to fi mu ki wọn dibo mo ni igbagbọ ninu rẹ fun ni gbogbo asiko laasigbo ẹsun ifipabanilopọ.
Bi awọn eniyan ṣe gba tirẹ fihan pe igbiyanju ati yọ nipo ko ni ipa buburu lori rẹ bii ti awọn asaaju rẹ mejeeji.












