Covid-19 vaccine in Nigeria: Abẹ́rẹ́ àjẹsára yóò wọ Naijiria láìpẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìjọba àpapọ̀ gbé ₦10b kalẹ̀ fún ìpèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 alábẹ́lé
Covid-19 vaccine in Nigeria: Abẹ́rẹ́ àjẹsára yóò wọ Naijiria láìpẹ́
Minisita eto ìlera, Osagie Ehanire ti sọ pé ìjọba àpapọ̀ ti gbe biliọnu mẹwaa naira kalẹ fún ìpèsè abẹrẹ ajẹsara labẹle.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Osagie ni Naijiria ti n ba awọn tó n po oogun náà sọrọ lori ìpèsè rẹ.
Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ nipa abala akọkọ abẹrẹ ajẹsara ti wọn yóò kó wọ Naijiria laipẹ ree.
Awọn ọmọ Naijiria ti yóò kọkọ gbà abẹrẹ ọhún ti ileeṣẹ Pfizer-BioNTech ṣe yóò gba abẹrẹ náà ni oṣù kẹta, ọdún 2021.
Ìparí oṣù Kejì ni ìjọba gbagbọ sọ pe ẹgbẹrun lọna ọgọrun abẹrẹ náà yóò balẹ sí Naijiria.
- Báwo ni èròjà Fáítámì D ṣe ń dáàbò bo àgọ́ ara wa?
- Ọlọ́pàá mẹ́rin kú, ọ̀kan dàwátì níbí ìkọlù tó wáyé ní Birnin-Gwari ní ìpínlẹ̀ Kaduna- Ọga Ọlọ́pàá
- Àlàyé rèé lórí bí ''Ice Cream'' ṣe lùgbàdì àrùn coronavirus bí èèyàn
- Ẹ wo ohun tí Seriki Fulani sọ fún gómìnà Makinde nípa Sunday Igboho
- Ó lé ní ọgọ́rin èèyàn tó kú nínú ìjà ẹlẹ́yàmẹ́yà tó wáyé ní Dafur- Aláṣẹ Sudan
Awọn wo ni abẹrẹ náà yóò kan?
- Awọn oṣiṣẹ eto ìlera
- Awọn adari to ṣe pataki
- Awọn ti iṣẹ wọn ṣe pàtàkì bíi àwọn òṣìṣẹ́ ni papakọ ofurufu
- Awọn ọlọpaa kan at'awọn aṣobode
- Awọn oṣiṣẹ ile iwosan ti wọn ti n ṣe ayẹwo Covid-19
- Awọn àgbàlagbà tó ti pé aadọta ọdún sókè
- Seyi Makinde pàṣẹ fún àwọn ọlọ́pàá láti wádìí Sunday Igboho lórí gbèǹdéke tó fún àwọn Fulani
- Àwọn agbébọn ti jí àwọn arìnrìnàjò gbé ní ìpínlẹ̀ Osun!
- Iyaafin Fọlakẹ Arẹmu, Orisabunmi ti wọ káà ílẹ̀ sún
- Àwọn agbébọn ti yìnbọn pa igbákejì akọ̀wé FUTA
- Gbogbo ẹ̀yin Fulani darandaran tó wà ní ìgbó ìjọba ní Ondo, ọjọ méje lẹní láti pòórá - Gomina Akeredolu
Ijoba apapọ ti sọ pé ọfẹ ni abala akọkọ abẹrẹ náà yóò jẹ fún àwọn ọmọ Naijiria.
Ẹwẹ, ìjọba àpapọ̀ tun ti n ba ileeṣẹ kan ni China jíròrò lórí bí wọn yóò ṣe kó mílíọ̀nù mejilelogoji abẹrẹ miran wọlé.
















