FUTA Deputy registrar's death: Àwọn agbébọn ti yìnbọn pa igbákejì akọ̀wé FUTA

Oríṣun àwòrán, @Amos
Igbákejì akọ̀wé FUTA jáde láyé lẹ́yìn tí àwọn agbébọn ṣàkọlù si lọ́nà Ilesha.
Awọn agbegbọn kan ti yinbọn pa igbakeji akọwe fasiti ìjọba apapọ to wa ni ilu Akure, FUTA, Ọmọwe Amos Arijesuyo, lagbegbe iwaraja, eyii to wa lopopona Akure-Ilesha.
Akọlu naa waye sí Arijesuyo to jẹ oṣiṣẹ ni ẹka ti wọn ti máa n gba awọn akẹkọọ nímọ̀ràn nílé ìwé náà lọjọ Àbámẹ́ta.
Yatọ sí Ọmọwe yìí, wọn tún yinbọn sí awakọ rẹ àti ọkunrin kan ti wọn ko darukọ.
Arijesuyo tun jẹ pasitọ ninu ijọ CAC, ẹka Glory of God, to wa ni waju nile ìwé náà.
Ọkan lára àwọn olùṣọ àgùntàn ìjọ ọhun, pasitọ Olu Aladesanmi tó fìdí iṣẹlẹ náà mulẹ fún àwọn akọroyin ni o waye ni nnkan bíi aago marun un si mẹfa irọlẹ ọjọ Sátidé.
O ni "ori lo ko pasitọ náà ati awakọ rẹ yọ ti wọn ko ba iṣẹlẹ naa lọ, bo tilẹ jẹ pé wọn farapa, wọn ti n gba itọju lọwọ nile ìwòsàn bayii."
Ẹwẹ, lẹhin wakati diẹ sí asiko naa ni Arijesuyo jade laye.
Nigba ti awọn akọroyin kọkọ kan sí alukoro FUTA, Adegbenro Adebanjo, o ni oun ko tii le fìdí iṣẹlẹ náà múlẹ.
Adegbenro sọ pe "n kò tíì le fi idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ nitori mi o tii gbọ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ṣugbọn ma a kan si yín laipẹ."
Ọpọ àwọn ọmọ ile iwe FUTA ati oṣiṣẹ lo ti n sọrọ nípa ìṣẹlẹ náà.

















