Cristiano Ronaldo: Gbajugbaja agbábọ́ọ̀lù Juventus àti Portugal ti lùgbàdì àrùn Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Coronavirus ti nawọ gan ilumọọka agbabọọlu nii Cristiano Ronaldo.
Ajọ elere bọọlu ilẹ Portugal Portuguese Football Federation, FPF, lo fi ikede yi sita.
Atẹjade ti wọn fi sita sọ pe agbabọọlu ni dun marundinlogoji naa n ṣe daada ni iyasọtọ ti ko si ṣe afihan arun naa kankan
- Màmá Guardiola d'olóògbé lẹ́yìn tó lùgbàdì Coronavirus
- Wo agbábọ́ọ̀lù Super Eagles Nàìjíríà àkọ́kọ́ tó lùgbàdì coronavirus
- Zlatan: Èyí mo ṣé tó, àsìkò tó láti tèsíwájú nínú ìrìnàjò mi
- Real Madrid ń gbáradì láti ra Paul Pogba pẹ̀lúu £70m
- Awo lọ? Messi ò lè dúró mọ́, aṣojú Manchester City ti balẹ̀ sí Barcelona láti dú ìná dúrà
- Ronald Koeman di akọ́nimọ̀ọ́gbá Barcelona tuntun lẹ́yìn ìjàmbá Champions League
Orileede Portugal yoo koju Sweden ninu ifẹsẹwọnṣe idije Nations League lỌjọru.
Awọn akẹgbẹ rẹ to ku ti wẹ yankankan lẹyin ayẹwo Covid-19 ti wọn yoo si kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn.
Portugal ati France gba ọmi ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba kẹyin lọjọ Aiku ti awọn ati France si jọ ni iye ami ayo kan naa lori afara.
Nitori iyasọtọ yi, Cristianno Ronaldo ko ni le kopa fun ẹgbẹ agbabọọlu rẹ Juventus lọjọ Kẹtadinlogun oṣu Kẹwa pẹlu Crotone.
Bakan naa ko ni le kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Juve ati Dynamo Kiev ninu Champios League logunjọ oṣu Kẹwa.













