Pogba: Ikọ̀ Real Madrid ń gbáradì láti kó £70m lé Paul Pogba lórí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ti n gbaradi lati ko aadọrin miliọnu pọun le atamatase ikọ Machester United, Paul Pogba lori.
Ọmọ ile Faranse ọhun ti sọ pe oun ko ni tọwọ bọwe adehun tuntun mii pẹlu ikọ Man United mọ lẹyin ti saa bọọlu yii ba ti pari.
Pogba ni oju oun ti kuro ni Machester United, ati pe yoo wu oun lati kẹru oun lọ si orilẹede Spain ki saa tuntun mii to bẹrẹ.
O ni ko si iye owo yowu ti Man United ba fi lọ oun, oun ko ni duro.
Ṣaaju ni Madrid ti gbiyanu lati ra agbabọọlu naa lọdun to kọja ṣugbọn idunadura ọhun fori ṣọpọn.
Everton: À ní se ìwádìí lóri ìgbẹ́sẹ̀ ti Moise Kean gbé lásìkò yìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Everton tí bẹnu àtẹ lù bí ọkan lára àwọn agbabọọlu wọn Moise Kean ṣe yọ lọ sí apejẹ kan lásìkò tí òfin konile o gbélé wà níta.
Iwe iroyin Daily Star Sunday lo gbe ìròyìn síta pe agbabọọlu náà tó ẹni ogún ọdún ya fidio ará rẹ níbi to tí n ṣe fàájì apejẹ nínú ilé rẹ.
Everton sọ pé ọrọ náà ṣe àwọn ní kàyéfì bí ọkan ninu ogbontarigi agbaboolu àwọn yóò ṣe tapa sí òfin ìjọba àti ìlànà ẹgbẹ náà lásìkò àjàkálẹ̀ Covid 19 yí.
"Ẹgbẹ wà fí ìbínú ṣàfihàn ifehonuhan wà sí agbabọọlu yi"
Wọn fi kun ninu atẹjade pé àwọn tí sáájú tẹpẹlẹmọ pàtàkì titẹle alakalẹ ìjọba tó fi mọ dideju mọlé lásìkò ta wa yí nípa atẹjade orisirisi fawọn oṣiṣẹ wà"
Wọn wà tun so pe awọn "gbosuba káre fawọn oṣiṣẹ ilera fún ifaraji wọn.
Ẹgbẹ́ náà sọ pé ọnà ati fi im'oore hàn ní kí oníkálukú bọwọ fún wọn nípa ṣíṣe ohun tó tọ"
Iye èèyàn tó ti tọwọ àrùn Covid 19 lo tí tó ẹgbẹrun ogun nilẹ gẹẹsi.
Kean ko se dáadáa ni saa akọkọ rẹ ni Premiership toun ti owó iyebiye tí wọn fi ra wa sí Everton lati Juventus,mílíọ̀nù meedogbon lè diẹ ní wọn rà tí kò sí ti gbá ju bọ́ọ́lù kan sáwọ̀n lọ ni sáà bọọlu yí.
Orúkọ rẹ ti kun àwọn agbabọọlu Premiership miran to tí tapa sí òfin konile o gbele lasiko yìí
Kyle Walker tí Man City n duro dè abajade iwadii eléyi tó n tọ pinpin bi o ti ṣe pé apejẹ nínú ilé rẹ pẹlu awọn obinrin oníṣẹ́ nàbì méjì kàn.Jose Mourinho ẹgbẹTottenham, Serge Aurier ati Musa Sissoko náà tapa sí òfin lọnà kan tabi omiran.












