Coronavirus update: Àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ìlẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fẹnukò láti parí líìgì ọdún yìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ẹgbẹ agbabọọlu nilẹ Gẹẹsi ti fohun ṣọkan pe awọn yoo gba awọn ifẹsẹwọnsẹ to ku ninu idije liigi tọdun yii ti arun Coronavirus da duro.
Nibi ipade kan to waye lọjọ Ẹti ni wọn ti gbe afẹnuko yii kalẹ bi o tilẹ jẹ pe wọn ko sọ igba kan ni pato ti wọn yoo pada bẹrẹ gbigba iyoku rẹ.
- Òfìfo ṣọ́ọ̀ṣì pa aṣọ dà fún àwọn Páṣítọ̀ Nàìjíríà
- Dánáfojúrà nìyí, abàmì eégún tí ń gbé inú iná ṣọlá
- Ìrìnàjò Toyin Abraham, láti orí gbèsè jíjẹ, ó di onílé, onimọto àti aya lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ
- Àwọn Alákòso gárèjì ló kó ìbọn àti àdá tọ ọlọ́kadà wá ní Soka-Alága ẹgbẹ́ ọlọ́kadà Ọyọ
- Ìjọba yóò lo BVN àtàwọn ọ̀nà méjì míràn láti pín owó ìrànwọ̀ fún aráàlú
- Yewande bí'mọ tuntun jòjòló, Mercy Aigbe pàdánù èèyàn rẹ̀, Toyin Abraham fèsì lórí aṣoju NCDC
- Ṣé Irọ́ ni pé àwọn adigunjalè ń ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Eko àti Ogun?
Ohun ti ọpọ lero ni pe awọn ẹgbẹ agbabọọẹu yoo jiroro lori boya ki wọn pada bẹrẹ ni ọgbọn ọjọ oṣu kẹfa ọdun 2020 ṣugbọn ilana ti wọn yoo fi to idije naa ni wọn jiroro le lori.
Ajọ to n ṣe aayan idije liigi ilẹ Gẹẹsi ṣalaye pe afojusun wọn ni lati pari awọn ifẹsẹwọnsẹ to ku.
Lati ọjọ kẹtala oṣu kẹta ni wọn ti gbe idije liigi ilẹ Gẹẹsi ti si ẹgbẹ kan nitori ajakalẹ arun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun ti agbọ ni pe awọn ẹgbẹ agbabọọẹu naa ni asiko kọ niyi lati jiroro boya ọgbọọjọ oṣu kẹfa ni ki wọn bẹrẹ tabi rara.
Ṣaaju ninu ọoṣu yii ni ajs liigi ilẹ Gẹẹsi ti ṣalaye pe o digba ti alaafia ba ti pada ki awọn to ṣi ilẹkun liigi pada. Lati igba naa titi di asiko yii, iye awọn to ku ni ilẹ Gẹẹsi ti le lẹbẹrun mejila.
Ninu eto idibo kan ti ileeṣẹ iroyin ere idaraya BBC Sport gbe kalẹ lori bi o ṣe yẹ ki wọn pari idije liigi, ida mọkandinlogoji ninu awọn to dibo naa fẹ ki wọn wọgile saa liigi yii, ida mejidinlọgbọn ninu ọgọrun fẹ ki wọn pari rẹ bi o ti wu ko pẹ to.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ ere bọọlu ilẹ Yuroopu ti rọ awọn ajọ to n ṣakoso liigi orilẹede kọọkan lati fun wọn ni asiko diẹ ki wọn fi yanju ọrọ lapa ọdọ tiwọn.
Lọsẹ to n bs ni ajọ UEFA yoo pade lati tubọ jiroro lori rẹ ninu eyi ti wọn fi n gbero ati lo aṣekagba idije Champions league fi pari saa ere bọọlu tọdun yii ni ọjs kọkandinlọgbọn oṣu kẹjọ.
Awọn liigi yooku nilẹ Yuroopu nkọ o?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ṣoju awọn eekan liigi ere bọọlu nilẹ Yuroopu sọ pe nigba yoowu ti wọn ba bẹrẹ si ni gba idije liigi kọọkan pada, wọn yoo maa se ilẹkun papa iṣire ni.
Liigi orilẹede Germany: awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti pada si papa igbaradi ṣugbọn wọn ṣi gbe liigi orilẹede naa kọ di Ọgbọọjọ oṣu kẹrin.
Liigi orilẹede Spain: ko ni si igbaradi kọkan ayafi igba ti wọn ba gbe ẹsẹ kuro lori awọn eto to wa nilẹ. Aarẹ ajọ liigi orilẹede Spain, Javier Tebas ni afaimọ ko maa di ọjọ kejidinlọgbọn ki wọn to bẹrẹ liigi pada nibẹ.
Liigi orilẹede Faranse: awọn alaṣẹ liigi lorilẹede Faranse n boju wo aarin ọjọ kẹta si ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹfa gẹgẹ bii ọjs ti wọn yoo bẹrẹ owo bọọlu gbigba pada lorilẹede naa.
Liigi orilẹede Italy: ajọ to n dari ere bọọlu lorilẹede Italy n gbero ati bẹrẹ ayẹwo awọn agbabọọẹu fun mims ẹni to ba ni arun coronavirus ninu wọn ni oṣu karun un ni igbaradi fun bibẹẹrẹ saa ligi wọn pada.












