Báwo lo ṣe lè di aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú "delegate" tó ń yan olùdíje ní Nàìjíríà?

Oríṣun àwòrán, Google
Lasiko eto oselu to n lọ lọwọ ni Naijiria, ariwo awọn aṣoju ẹgbẹ́ oselu, Delegates, ni gbogbo ayé n pa.
Eyi ko sẹ́yìn ipa pataki ti wọn n ko ninu yiyan oludije ti yoo soju ẹgbẹ́ kọọkan lọ́dún 2023.
Iroyin nipa bi awọn oludije ṣe n ṣe ipade pẹlu awọn aṣojú, lati le beere fun atilẹyin wọn, paapaa ninu ẹgbẹ́ oselu meji gboogi ni Naijiria, APC ati PDP, n jade lojoojumọ.
Ninu ofin eto idibo tuntun, aaye wa fun àwọn ẹgbẹ́ oṣelu lati yan oludije wọn ni ọna to ba wu wọn - idibo, tabi fifẹnuko yan oludije kan ṣoṣo.
Ilana lilo idibo awọn aṣoju si ni ẹgbẹ́ oselu gboogi mejeeji yan laayo.
Awuyewuye to n waye lori ọrọ awọn aṣoju yii, lo mu ka fẹ ẹ ṣe agbeyẹwo iru eeyan ti wọn jẹ, ati ipa ti wọn n ko ninu ẹgbẹ́ oṣelu.
Àwọn wo ni 'delegates' ẹgbẹ́ òṣèlú?

Gẹ́gẹ́ bi aṣoju ẹgbẹ́ oselu kan ninu PDP, Jikume Bethlehem, ṣe sọ fun BBC Pidgin, awọn aṣoju ẹgbẹ́ jẹ ọmọ ẹgbẹ́ oselu, àmọ́ ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ dibo yan lati soju wọn dibo ninu yiyan àwọn oludije lasiko ibo abẹnu.
Ẹnikẹni to ba ni ibo to pọ ju níbi ibo abẹnu, ni yoo ṣoju ẹgbẹ́ oselu wọn.
"Ẹẹkan pere si ni eeyan le jẹ 'delegate', ayafi ti wọn ba tun dibo yan lasiko eto idibo gbogbogboo míì."
Báwo lo ṣe le di aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlù?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọ ẹgbẹ́ oṣelu to ni kaadi ẹgbẹ lo le di aṣoju. Wọn si ma n dibo yan wọn ni.
Amofin Maliki Quliya, ti oun naa jẹ aṣoju ninu idibo apapọ ẹgbẹ́ PDP sọ pe lati ijọba ibilẹ 774, to wa ni Naijiria, ni aṣoju kọọkan yoo ti wa.
Àwọn wọn yii ni yoo yan ẹni ti yoo dije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ́ oṣelu wọn.
Ni ipinlẹ, awọn aṣojú mẹta ni yoo wa lati wọọdu kọọkan, lati yan àwọn oludije si ipo aṣofin ipinlẹ, ile igbimọ aṣoju-ṣofin, awọn sẹnetọ ati awọn gomina.
Ṣé àwọn 'delegate' ma ń gba owó kí wọ́n tó dìbò?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn iroyin to n lọ lori ayelujara sọ pe obitibi owo ni awọn 'delegate' n gba lọwọ àwọn oludije ṣaaju idibo abẹnu.
Igbakeji alaga ẹgbẹ́ PDP nijọba ibilẹ Ariwa Kano, Hashimu Sulaiman sọ pe diẹ lara awọn iroyin jẹ otitọ, àwọn kan si jẹ ayederu.
"Ni ipinlẹ Kano fun àpẹẹrẹ, àwọn aṣoju ni olórí, oun ni yoo si sọ ẹni ti gbogbo wọn yoo dibo fun."
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti yan gbogbo awọn oludije rẹ bayii, nipa idibo awọn aṣoju ẹgbẹ́.
Atiku Abubakar si ni wọn yàn lati dupo aarẹ Naijiria lọ́dún 2023.
Opin ọṣẹ yii ni ẹgbẹ́ APC yoo yan ti wọn.















