Ìdí rè é tí Ọlọ́wọ̀ ti ìlú Ọ̀wọ̀ fi rọ Olóyè Olanipekun lóyè…

Oríṣun àwòrán, Olowo of Owo Leadership Colloquium
Ọlọwọ ti ilu Ọwọ, Oba Ajibade Gbadegẹsin Ogunoye III ti sọ idi ti oun fi yọ, Oṣere ti Ẹhin-Ogbe, Oloye Ololade Olanipekun ni ipo.
Ọba Ogunoye ni oun rọ ó ni ipo nitori aibọwọ fun asa ati iṣe eleyii to tọ si ọba ni ilẹ Yoruba.
Wọn ni oloye naa hu iwa aitọ niwaju ọba, eleyii to tumọ si igberaga ati aibọwọ fun ori ade.
Ọba Ogunoye ni eleyii fihan pe oloye naa ko ni imọ nipa itan, asa ati iṣe ilu Ọwọ.
Titi di asiko yii, Oloye naa kọ lati ṣe atunṣe tabi gba wipe oun ṣe ohun ti ko tọ, eleyii to fi igberaga ninu ihuwasi re han.
Ninu atẹjade to fi idi iyọkuro nipo naa mulẹ, ni wọn ti yan Osunnla ti Ehin Ogbe, ko jẹ olori agbegbe naa ni kiakia lati rọpọ oloye ti wọn yọ nipo.
‘’Oloye Olanipekun ni a ti yọ nipo ni alailọjọ, nitori o kọ lati bọwọ fun ori ade ti ko si tẹle asa ati iṣe Edibo Ologho pẹlu iwa aitọ lasiko ipade awọn afọbajẹ , Ọlọwọ in- Council ni ilu Ọwọ.’’
''Bakan naa ni a fun oloye naa ni anfaani lati tọrọ aforiji, amọ o yari to si n sọ wi pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, amọ niṣe lo kọ jalẹ to si tun ba orukọ, asa ati iṣe ilu naa jẹ kiri.''

Atẹjade naa tẹsiwajupe ''nibayii ti a si ti mọ pe ko ṣetan lati tọrọ idariji tabi bẹbẹ, ko si ohun ti a le ṣe ju ki a rọ ni ipo, ko si ma jẹ oloye ni ilu Iwo.''
''Lẹsẹkẹsẹ naa ni a si ti paṣẹ ki o ma pe ara re ni oloye ilu Ọwọ mọ tabi wọ akun ti oloye mọ.''
Lakotan, wọn ni Oloye Adebayo Adeyemi to jẹ OSUNLA ti Ehin-Ogbe to jẹ ẹni to tẹle oloye ti wọn yọ ni ipo yoo ṣakoso agbegbe Ehin Ogbe lai si ani-ani ninu rẹ.















