Àṣẹ ni Ààrẹ Buhari pa fún àwọn gómìnà kò bẹ̀bẹ̀ lórí yíyàn ààrẹ Naijiria lọ́dún 2023- Festus Adedayo

Aworan aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Facebook/MuhammaduBuhari

Ọ̀rọ̀ n bọ̀rọ̀ bọ̀ lori ase Buhari fawon gomina.

Onimọ nipa ọrọ eto oṣelu ni Naijiria, Festus Adedayo ti ni ko tọna bi Aarẹ Buhari ṣe kesi awọn gomina lati dibo yan ẹni ti oun yoo fa silẹ lati rọpọ oun gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria.

Eyi ko ṣẹyin ipade ti Aarẹ Buhari ṣe pẹlu awọ̣n gomina lati inu ẹ̣gbẹ̣ oṣelu APC, pe ki wọn fun oun ni aaye ati ifọwọ̣sowọpọ pẹlu oun lati yan ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ oselu naa ninu ẹto idibo abẹle ti o n bọ.

Adedayo to jẹ onwoye oṣelu ni aarẹ Buhari sọrọ bi ẹni pe oye idile ni ipo aarẹ lorilẹede Naijiria, ti eniyan si le fa ẹni to ba wu u silẹ, o ni aarẹ ko lẹtọ lati ṣe eyi.

‘’Ṣe oye idilẹ ni aarẹ Buhari fẹ sọ oṣelu Naijiria da ni? Eto oṣelu tiwantiwa la n ṣe ni Naijiria kii ṣe ijọba ologun.’’

‘’Ninu iṣẹ awọn ologun, nkan ti aarẹ ba sọ ni abẹ gẹ. Ni ti temi, aarẹ fẹ ka pada si ẹsẹ aarọ, nipa ti ologun’’

’Aarẹ fẹ ṣe bi Ologun le awọn eniyan lori, eto oṣelu tiwantiwa ko si fi aye gba nkan ti aarẹ Buhari fe ̣se’’

‘’Gbogbo awọn gomina ti aarẹ Buhari jọ ṣe ipade pẹlu, ko si ẹni to le gbena woju aarẹ ninu wọn.’’ ‘’Lerefe, o dabi ẹni pe aarẹ n rọ wọn ni, amọ ti a ba wo oro naa finifini,oun pase fun won ni. ‘’

Aworan aarẹ Buhari ati awọn Gomina APC kan nibi ipade

Oríṣun àwòrán, Facebook/MuhammaduBuhari

Bakan naa ni onimọ nipa eto oṣelu naa bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti Aarẹ sọ lati gboriyin fun iwa aitọ ti awọn gomina n sẹ ni ipinlẹ wọn.

O ni iwa lati ma a yan ẹni ti o ba wu wọn lati rọpo wọn ti wọn ba kuro ni ipo ko dara to, to si ni nkan ti wọn n ṣe ni awọn ipinlẹ wọn naa ni oun fẹ sẹ.’’

‘’Aarẹ fi ontẹ tẹ iṣẹ laabi ti awọn gomina n ṣe ni iṣakoso ipinlẹ wọn ni.’’

‘’Awọn ti wọn fẹ di ipo mu ti bẹrẹ si ni na owo -nara, amọ ṣadede ni gomina ilu a sọ wipe ẹni bayii ni oun fẹ ti yoo si jẹ ẹni ti yoo ba wọn fi ọwọ bo gbogbo kudiẹ-kudiẹ iṣejọba wọn ni.’’

Onimọ nipa eto oṣelu naa wa fikun un pe ohun ti awọn eniyan kan n sọ ni pe aarẹ fẹ bu omi tutu si ọkan awọn eniyan.

O ni pe eyi ko seyin nitori ẹni to fẹ ko jẹ aarẹ kii ṣe ẹni ti awọn gomina fẹran, to si dabi ẹni pe aarẹ fẹ fi ontẹ lu ẹni naa.