Ẹ̀ fọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú mi láti yan ẹni tí yóò rọ́pò mi - Buhari sọ fún àwọn gómìnà APC

Aarẹ Muhammadu Buhari pẹlu awọn Gomina ẹgbẹ oselu Apc

Aarẹ orile-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti sọ fun awọn gomina lati inu ẹgbẹ oselu All Progressive Congress (APC) lati fun oun laye ati pe ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu oun lati yan ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ oselu naa ninu ẹto idibo abẹle ti o n bọ.

Aarẹ Buhari sọ eleyi di mimọ nibi ipade ti o waye pẹlu awọn gomina APC ni ọjọ Isẹgun ni ile ijọba to wa niluu Abuja.

Ninu Ipade naa lati ri alaga ẹgbẹ oṣelu lorilẹede Naijiria, Abdullahi Adamu ati awọn agba ọjẹ ninu ẹgbẹ oṣelu naa.

Aarẹ ni ojuṣe oun ni lati gbaruku ti ẹgbẹ oselu APC nibi eto idibo abẹle ati lati rii pe ẹgbẹ oṣelu naa jawe olubori ni eto idibo ọdun 2023.

“Bi a ṣe n mura fun eto idibo abẹle ẹgbẹ oselu APC, mo rọ lati awọn gomina ati awọn agba ọjẹ ninu ẹgbẹ lati fọwọsowọpọ pẹlu mi lati yan Aarẹ ti yoo gbe asia ẹgbẹ oṣelu APC lati di Aare orile-ede tuntun ni ẹto idibo ọdun 2023.”

Aarẹ tesiwaju pe ifọwọsowọpọ awọn gomina naa ni o mu ki ẹgbẹ oṣelu APC tayọ ninuu eto idibo ọdun 2023.

“Erongba ẹgbẹ ni lati bori awọn akẹgbẹ wọn fun idi eyi a gbodo yan ọmọ oye ti yoo fun awọn ọmọ orile-ede ni apẹrẹ aṣeyọri ati ifokanbale ki idibo ọdun 2023 to waye.”

Lẹyin ipade pẹlu awọn gomina ni Aarẹ Buhari mori le orilẹede Spain.