Ohun tí àwọn òsèré Nollywood ń sọ nípa akẹgbẹ́ wọ́n,Gbadebo Osmond tó kú rèé

Aworan osere tiata to jade laye Osmond

Oríṣun àwòrán, Instagram/osmondebo

Àkọlé àwòrán, Oludari fiimu ni Osmond ti o si lajọṣepọ pẹlu awọn oṣere Yoruba

Awọn oṣere Yoruba ni Nollywood ti bẹrẹ si ni ṣedaro ọkan lara wọn, Osmond Gbadebo to dologbe.

Gbadebo to jẹ gbajugbaja oṣere to tun ma n gbe fiimu jade, lo jade laye ni Ọgbọnjọ, Oṣu Karun, ọdun 2022.

Gbajugbaja oṣerebinrin Fausat Abeni ti ọpọ eniyan mọ si Madam Saje pẹlu awọn to kọkọ kede iku rẹ lori Instagram nibi to ti n ṣe idaro oloogbe naa.

Ninu akọjade naa lo ti ni ‘’ Odaarọ Osmond’’ pẹlu awọn ''emojis'' to ṣafihan ẹkun kikoro ati omije loju pẹlu imọlẹ to tan.

Ohun ti awọn oṣere Nollywood n sọ ree nipa akẹgbẹ wọn,Gbadebo Osmold to ku

Aworan osere tiata to jade laye Osmond

Oríṣun àwòrán, Instagram/osmondgbadebo

Oṣerebinrin Bakare Zainab ti ko le e fi mọra ni Osmond kilo de to o fi jade laye.

‘’Mo ko awọn fidio yii jọ lati fi ṣe ayajọ ọjọ ibi re ati ti ọmọ bibi inu rẹ amọ ti o ni ki n ma fi si ori ayelujara. ‘’

‘’Osmond kilo de to o fi ọmọ ọsẹ meji silẹ si aye lọ? Kilo de ti o ṣe eleyii si awọn ololufẹ rẹ, kilo de ti iku mu o lo ni Osu Karun un, Osu May to jẹ Osu ibi rẹ, ti ọmọ rẹ, amọ nibayi to ti di oṣu ti o jade ni aye.''

Aworan latiu oju opo Laide Bakare

Oríṣun àwòrán, Instagram/laidebakare

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn oṣere miran ti wọn tun ṣedaro rẹ ni Yomi Fabiyi, Adeniyi Johnson ati awọn miran bẹẹ bẹẹ lọ.

Fabiyi ni iku Osmond ṣe ni laanu ti o si dun oun de egungun. O ni bio tilẹ jẹpe o ja fitafita fun ẹmi rẹ, amo o ti lo simi.

O ṣapejuwe Gbadebo bii apanilẹrin to si ma n ṣe aduroti fun awọn akẹgbẹ rẹ lọna kọna.

‘’Sun re o ninu agbara ati alaafia’’

Johnson ni tirẹ ni eleyii ba oun gidi ti oun ko si le fi aworan rẹ sita nitori pe gbogbo eniyan to yi ounka lo mọ bi oun ṣe fẹran rẹ to amọ ki ba ma jẹ oun.

Ronke Oshodi ti apeja orukọ rẹ n jẹ Ibironke Ojo Antony ni o ṣoro fun oun lati sọ wi pe o daarọ amọ igbagbọ ni wi pe Ọlọrun mọ nipa rẹ. Sun re o.

Ninu ọrọ tirẹ, oṣerebinrin Bimbo Success ni ile aye asan ninu asan ni, ki Osmond ma a sinmi titi ayeraye.

Awọn miran to jẹ oṣere ti wọn fi idaro ranṣẹ si ni Fathia Balogun, kitan, Laide Bakare, Afeez Owo, Omowunmmi Ajiboye to fi mọ Kunle Afod.

Lara awọn fiimu ti o ti kopa ni Ẹwọn Ifẹ, Queen Lateefat, Ẹdunjọbi, Hired Killer ati bẹẹ bẹẹ lọ.