Ẹgbẹ́ òsèlú APC yọwọ́ olùdíje mẹ́wàá kúrò láwo àwọn tó máa díje dupò aàrẹ Nàìjíríà

Igbimọ awo gbe abajade awo le alaga APC lọwọ

Oríṣun àwòrán, OfficialAPCNg

Bi eto ididbo ọdun 2023 se n sunmo tosi ni Naijiria ni orisiirisii nkan ti n sẹlẹ̀.

Egbẹ́ oselu All Progressives Congress to n tukọ̀ Naijiria lọ́wọ́lọ́wọ́ lo ti seto ayẹ̀wo lati yan ọmọ oye ti yoo dupo aare labẹ asia ẹgbẹ́ APC.

Iroyin to jade bayii ni pe ọmọ oye mẹ́tàlá ni igbimọ to n se ayẹ̀wo naa ti fun ni iwe o – pegede lati dije dupo fun APC.

Nigba ti won yọwọ́ awọn ọmọ oye mẹ́waaa kuro lawo pe wọn ko koju osuwọ̀n tó.

Lara idi ti wọ́n fi yọ awon mẹ́waa naa ni pe wọ́n ko fẹ́ enikeni to ba n jẹ́jọ́ lọ́wọ́ nile ẹjọ́ kankan lati soju egbẹ́ naa.

Bakan naa ni igbimo naa ti Oyegun jẹ́ Oludari wọ́n salaye pe awọn ọmọ oye miran funra wọn ni wọ́n sọ pe awọn ko dije mọ́ lasiko ayẹ̀wo naa.

Idi ti awọn wọ̀nyii só nipe awọn ti dagba nipa wiwo ọjọ́ ori ati agbara lati koju ipenija to le jade lasiko eto idibo ọdun 2023.

Yemi Osinbajo lasiko to n se ayẹwo fun ipo oludije ipo aarẹ

Oríṣun àwòrán, Yemi Osinbajo

Alaga John Oyegun salaye pe oludije mẹ́tala pere lo ni anfani lati dije labe egbẹ́ APC.

O ni awon oludije metalelogun lo wa fun ayewo saaju eto idibo abenu APC to maa waye lose to m bo.

Awon igbimo ayewo APC yii kọ lati fi orukọ awọn oludije ti wọ́n yọ kuro sita.